Lati Owo Akoroyin Olootu
Aye yii ma ti waa baje o! Owo te Sunday ati Laudu nibi ti won ti n ba ara won sun n'Ibadan
Nitori pe won ka won mobi ti won ti n huwa to buru jai, to si le da omi alaafia ilu ru nipa biba ara won lo po, ileese olopaa ipinle Oyo ti taari awon okunrin meji kan, Sunday Gabriel, eni odun merindinlaaadota ati Audu, eni ogun odun sile-ejo majisreeti to n jokoo n'Iyaganku, niluu Ibadan, ni yara igbejo kerin, niwaju Adajo K.Y Durosaro Tijani lati so tenu won.
Nigba to n safihan won fun ile-ejo, agbejoro ijoba, Inspekito Oluyemi Eyiaromi, fesun kan awon okunrin mejeeji naa pe lojo kokanlelogbon, osu to koja, ni nnkan bii aago marun-un owuro ni adugbo Railway Sango, niluu Ibadan, ni Sunday ati Laudu ti huwa ti ko ye omoluabi pelu bi awon gende mejeeji se n ba ara won sun, ti okan ninu won si ti nnkan omokunrin re bo ekeji ni iho idi. O ni esun yii tako abala kan ninu ofin to de iwa odaran nipinle Oyo, todun 2000, bee nijiya nla si wa fun un pelu.
Nigba ti won bi Sunday leere, se lo ni oun ko jebi esun naa pelu alaye, sugbon Laudu n gbonri ni tie, o loun ko gbo ede geesi ti won ka foun nile-ejo, afi ede Hausa nikan.
Niwon igba ti ko si si ogbufo ti yoo tumo ede geesi si Hausa fun Audu, Adajo K.Y Durosaro Tijani ni ki won si loo fi won pamo satimole olopaa, o sun igbejo sojo ketala, osu yii.