Gbagede Yoruba
 

 
Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba
 
Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo Itan Bi Ladoke Akintola She Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba

Oro awon oloshelu, too too too ni. Paapaa ni ile Yoruba yii, oro awon oloshelu too too ni. Ni 1964, opolopo eeyan ko ranti oye Aare Ona Kakanfo mo rara. Elomiiran ko tile gbo o ri, won o si mo ohun ti won n pe bee. Bee agbalagba ni won, awon mi-in ninu won si ti le ni omo adorin (70) odun daadaa. Ko le she ko ma ri bee, nitori eni to je Aare Ona Kakanfo yii gbeyin ko too di 1964 yii, Momodu Obadoke Latoosa, eni ti gbogbo aye pada mo si Aare Latoosa ni. Ojo keta, oshu kewaa, odun 1871, lo di aare naa, oun si ni Aare Ona Kakanfo to je gbeyin, nitori lasiko re ni Ogun Ekiti Parapo ti won tun n pe ni Ogun Kiriji waye, ogun naa ko si pari titi ti awon oyinbo fi de. Awon oyinbo funra won ni won pari ogun naa, ti won si shofin pe ko gbodo tun si ija tabi ogun eleyameya laarin awon Yoruba, tabi ni ibi gbogbo ni Naijiria mo.

Nidii eyi, nigba to she pe o din die ni ogorun-un odun ti won ti je Aare Ona Kakanfo yii gbeyin, opo eeyan ni ko ranti mo, afi awon ti won ba n ka iwe itan ile Yoruba nikan. Sugbon ni 1964, awon oloshelu hu kinni naa yo pada, Alaafin Gbadegeshin Ladigbolu si fi Samuel Ladoke Akintola she Aare ile Yoruba ninu oshu kejo, odun naa, oro naa si mu idunnu pupo ati ironu pupo dani fawon eeyan. Bawon kan ti n dunnu pe kinni naa daa, bee lawon mi-in n ronu pe eeti je, kin nitumo oye yii, ki lo si de to je Ladoke Akintola ni won gbe e fun. Oro naa mu awuyewuye ati opolopo ariyanjiyan dani, kaluku shaa fee mo idi abajo ni. Sugbon boya eni kan fe, boya eni kan ko, Akintola ti di Aare-Ona Kakanfo fun ile Yoruba, ko si si ohun ti enikeni le she si i. Ko tie kuro lori ipo naa titi ti olojo fi de ba a ninu oshu kin-in-ni, odun 1966, o lo oye naa titi digba naa ni.

Ko too di igba ti oun je yii, bi eeyan yoo ba tu itan naa seyin die, oun ko lakoko. Oba kan ti je ni aafin Oyo ri to je oba alagbara, ara oto ninu awon Alaafin si ni. Ajagbo loruko re, eyi ni won she n pe e ni Alaafin Ajagbo. Nigba ti won bi i, ibeji ni won bi i, Ajampati loruko ekeji re. Awon mejeeji jo ara won debii pe won aa maa shi won mu sira won, ti awon eeyan yoo si maa ke kabiyesi fun ekeji re, lai mo pe ki i she Alaafin ni won ki. Ko too di oba, jagunjagun gbaa ni, o si laya, bee lo gboju, ko si ibi ti ogun ti le ti e ko ni i ba a. O ni ore kan, okunrin kan ti won n pe ni Kokoro-gangan lati ilu Iwoye, won ti n ba ara won bo pe gan-an. Boya ogbon atorunwa ni o, tabi irin-ajo re to ti rin kaakiri, nigba ti Ajagbo di Alaafin, o mu nnkan tuntun wonu ijoba ilu Oyo. Bii odun 640 lo ti joba, ko si tun si Alaafin to pe bii tire lori oye, nitori ogoje (140) odun lo lo nipo Alaafin.

Okunrin yii lo da igbimo apashe, tabi igbimo awon to n shelu, sile ninu ijoba Oyo, asiko to si da a sile yii, ko ti i si iru nnkan bee niluu oyinbo paapaa, gege bi itan awon naa ti she so. Ninu awon eto tuntun to mu wo inu ishejoba ni akoso awon omo ogun re. Ki oun too de, awon omo ogun yii maa n po kaakiri, ti won yoo si wa labe Balogun agbegbe kookan. Loooto Balogun to wa niluu Oyo lo ye ko je olori awon Balogun gbogbo, sugbon awon Balogun mi-in laya, won si loogun debii pe won le wo oju Balogun Oyo nigba mi-in pe Balogun lawon naa, Balogun kan ko si ju Balogun mi-in lo. Eyi ni Alaafin Ajagbo she da ipo Aare-Ona Kakanfo sile, o si fi i lele pe ki i she omo Oyo nikan loye naa to si, olori ologun, tabi jagunjagun to dangijia julo, ni yoo maa je oye naa, ibi yoowu ko ti wa. Aare Ona Kakanfo yii ni yoo si je olori ologun gbogbo fun ile Yoruba pata.

Eni to ba mo oju Ogun ni i pa obi n'Ire, Alaafin Ajagbo ko reni ti yoo gbe ipo naa fun ju ore re lo, iyen Kokoro-gangan to n gbe ilu Iwoye, pe oun gan-an ni ipo Aare Ona Kakanfo yii to si. Lakooko, jagunjagun nla ni, o si mo on pe ore oun ni, ati pe ko le da oun, nitori ko tun si alagbara bii tire, agbara to si wa lowo aare yii le debii pe bo ba koju ija si Alaafin nile Yoruba nigba naa, nnkan yoo she. Alaafin ni olori ijoba loooto, owo re si ni agbara wa, sugbon Kakanfo ni olori awon omo ogun, oun ni gbogbo omo ogun si n gboro si lenu, koda, bi Alaafin duro sibe, ko si omo ogun ti yoo gboro si i lenu, ashe ti aare ba pa ni won yoo tele, ohun to ba so pe ki won she ni won yoo she. Agbara nla ti Aare ni lowo yii ni Ajagbo she so pe ko gbodo gbe aarin ilu pelu Alaafin, ko ma di pe alagbara meji yoo maa tako ara won. Oun ni olori gbogbo Balogun, ko si seni to le da ashe re koja.

Eto ijoba ti Alaafin Ajagbo gbe dide yii mu nnkan dara, paapaa nigba to je asiko ti awon omo ogun Ibariba n yo Oyo Ile lenu ni. Kia ni Aare yii sha awon Balogun to ku jo, to si ko won lohun ti won yoo she. Kia ni won reyin awon ogun Ibariba yii, won si le won jinna debii pe eekookan lo ku ti won n yoju. Eleyii fi ese Kokoro-gangan mule gege bii Aare Ona Kakanfo, nigba to si je gbogbo igba to fi wa nipo naa, ko si ogun ti ko bori, dandan ni fun aare yoowu to ba wa lori oye lati maa shegun. Aare to ba lo sogun ti ko shegun ohun, dandan ni ko she bii okunrin. Sugbon ki i saaba waye pe aare kan lo sogun ko shegun, nitori bi opolo ko ba fi le dun lobe, tapa-titan re ni yoo re si i. Aare Ajagbo ati Kokoro-gangan yii ni won pin awon omo ogun ile Yoruba si ona nla merindinlogun, ati ona wewe merinlelaaadota. Awon wonyi ni gbogbo omo ogun ile Yoruba wa labe won.

Leyin ti Kokoro-gangan lati Iwoye fipo naa sile ni Oyatope tun je, Iwoye yii loun naa ti wa. Leyin tiwon ni Oyabi lati Ajashe, Adeta lati Jabata, ati Oku lati Jabata bakan naa. Afonja Laya-loko lo je lati ilu Ilorin, ko si si eni ti ko mo ibi ti itan Afonja ti bere, ati ibi to pari si, nitori oun ni idi ti Ilorin fi bo kuro lowo awon Yoruba, to di ibi ti Fulani ti n she oba won. Aye Afonja gege bii Aare Ona Kakanfo ni wahala ba ile Yoruba, ti ijoba Oyo si daru, ti ijoba naa ko si ni isinmi titi ti won fi fa a ya. Leyin tire, ati leyin opolopo wahala ati idaduro, Toyeje lati Ogbomosho ni won gbe ipo naa fun, ko too waa kan Edun lati Gbongan, leyin ti yoo ti ku tan. Amepo lati Abemo lo je leyin Edun, eyin tire lo si kan Kurumi Ijaye, Kurumi okunrin dan-in dan-in. Ojo Aburumaku lo je lati Ogbomosho, omo Toyeje to ko je Aare lati ilu naa ni, oun naa si wa nibe pe titi.

Aare to je gbeyin ni saa yii ni Aare Latoosa, lati ilu Ibadan loun ti wa. Ni akoko ti Latoosa je yii, Ibadan ni ile agbara fun Yoruba, nitori awon omo ogun Ibadan yii ni Alaafin funra re gbojule lati she ohunkohun. Nidii eyi, ko shoro rara fun Latoosa lati di aare, nigba to je oun ni olori gbogbo jagunjagun won, ti Ibadan si je olori ilu ajagun ile Yoruba. Tipatipa lo tile fi di Aare Ona Kakanfo yii, nitori ki i she pe aare to wa nibe, iyen Ojo Aburumaku, ti ku. Aburumaku wa laye, sugbon Latoosa ranshe si i pe ko ko gbogbo nnkan oye ati opa ashe Aare Ona Kakanfo ranshe soun n'Ibadan, ti ko ba fe ki ile ga ju oun lo. Ojo Aburumaku ko lagbara Ibadan, o mo pe bi Latoosa ba binu, ko si ibi ti oun yoo gba, ko seni ti yoo gba oun lowo re, alagbara kan shaa ju alagbara mi-in lo. Iyen ni Ojo Aburumaku fi gba fun Olorun, o si ko gbogbo eelo naa ranshe pata. Nigba to di ojo keta, oshu kewaa, 1871, won fi Latoosa je Aare-Ona-Kakanfo ni gbangba ode.

Ni ojo kefa to joye lo fi Ajayi Ogbori-efon je Balogun re, to si fi Laluwoye je Otun Balogun. Sugbon won o ti i jokoo rara nigba ti ogun Ekiti Parapo bere, nigba ti Ogedengbe shaaju awon Ijesha, ti won darapo mo awon Ekiti ati Efon, ti won mura lati yo ara won kuro ninu igbekun awon ara Ibadan, nitori labe won ni won wa lati ojo pipe, ti won si koju ogun si won. Lati Ibadan titi wo agbegbe awon Ijesha ati Ife, titi wo awon Ilu Ekiti, abe Ibadan ni won wa, Ibadan lo n pashe fun won, ko si si ohun ti awon eeyan naa le da she lai je pe Ibadan fun won lashe. Ajaga yii lawon eeyan naa fee ko, ni won ba bere ogun gidi. Ogedengbe lo da kinni naa sile, nitori oun lo fee fi Odigbadigba je Owa Ilesha, sugbon awon Ibadan fi elomiiran je, won si be Odigbadigba lori ni Ibadan, won ni oku ki i je Owa, ko fi eni ti awon fi sipo naa sile ko maa shejoba re lo.

Eleyii lo bi Ogedengbe ninu, toun naa fi loo ko ogun ja Ilesha, to si le Owa ti awon Ijesha fi sori oye naa danu. Arifin pata lawon Ibadan ka eleyii si, pe Ogedengbe yoo da ashe ti awon Ibadan pa koja bee yen, yoo le eni ti awon fi sori oye danu, won si mura lati mo ohun to n ki i laya gan-an. Balogun Ajayi Ogbori-efon ko awon omo ogun re jade n'Ibadan ninu oshu kejila, 1872, won n wa Ogedengbe lo. O ku dede ki won wo Ilesha ni Ogedengbe sa mo won lowo, o si koja si inu igbo Ekiti lohun-un. Bee lawon omo ogun Ibadan gba Ilesha pada, won tun gba awon ilu mi-in, won ko si deyin leyin Ogendengbe, won n wa a kaakiri. Ogedengbe tan won wo inu igbo Ekiti, o duro de won ninu igbo Alawun, nitosi Ikere, nibe lo si ti dana fawon omo ogun Ibadan ya, o foju won ri mabo. Sugbon ibi ti ogun Ekiti ti bere naa ree, ogun ti won fi opolopo odun ja.

Lati igba ti won ti bere ogun yii ni 1872, to je bi won ti n ja okan ni omi-in tun n ruwe, titi ti enu awon Ekiti ati Ijesha fi ko pe awon ko ni i she eru fun Ibadan mo, ko si eyi to sheyin Aare Latoosa. Oun gan-an ni apashe ogun yii, oun lo si n dari won bi won yoo ti she jagun naa. Adelu ni Alaafin igba naa, abe re ni Latoosa ti bere si i she aare. Amo ko pe leyin naa ti Adelu fi waja, ti Adeyemi akoko si doba ni 1875, Adeyemi lo si wa lori oye ni gbogbo igba ti Latoosa n lo agbara re. Latoosa lawon oyinbo bere si i ba soro nigba ti ogun naa feju tan, oun lawon ashoju oyinbo gbogbo n ri, ti awon naa si n kowe sawon oyinbo yii lori ogun Ekiti parapo to n lo naa, o si ku gegere ki won yanju oro naa, iyen ni bii oshu mefa si akoko ti ohun gbogbo yoo yanju ni Latoosa ku lojiji, o ku nigba ti enikankan ko ro pe yoo she bee lo. Iyanu ni iku re paapaa je fun opo eeyan.

Leyin ti Latoosa ti ku bayii, oro ogun ko shele mo, nitori bii oshu mefa to ku ni won pari ija naa, ti won si towo bowe adehun, ko si tun si eni to gbodo jagun kankan mo pelu ara won. Nidii eyi, ko si ipo aare kankan mo, nigba to je oye ologun ni, ti ko si si ogun mo, ko senikan ti won tun le ni ko waa she aare. Ni asiko naa, awon oyinbo ti de, won ti n shejoba kaakiri, won si ti n fi ese ijoba won mule, bee ni won n fi agbara awon shoja tiwon mu awon jagunjagun ati awon araalu tabi oba to ba fee she agidi, ko si si eni to fee ko sowo oyinbo ninu won. Awon jagunjagun ti awon oyinbo n lo, awon jagunjagun ile Yoruba naa wa ninu won, sugbon awon oyinbo ni olori ogun tiwon funra won, ko si oyinbo ti yoo fi eeyan dudu kan she Aare Ona Kakanfo, tabi olori ogun re, nitori puruntu ni won ka gbogbo won si.

Nigba naa ni oye Aare Ona Kakanfo yii pare, nitori awon shoja oyinbo lo ku to n dari ogun, awon oyinbo funra won ni won si n shejoba, ko si si ohun ti won yoo fi oye yii she. Koda, awon ko ni Balogun tabi Ajagunna, gbogbo awon oye yii ni won ti so di oye omowe, sajenti tabi mejo leeyan yoo maa gbo, awon jagunjagun ile Yoruba naa si gbe jee. Ni odo Alaafin ati lodo awon oba to ku paapaa, ko seni ti i yan Balogun nitori ko le loo jagun, Balogun ti yoo kan ri si aabo ilu pelu awon omo ode ni, ko si Balogun ti i lo sogun. Kerekere bee ni oye Aare Ona Kakanfo yii n lo, ti awon eeyan si n gbagbe re, nitori ko si ogun, ko si si ijoba lowo Alaafin funra re mo, ijoba ti bo sowo awon oyinbo ti won n shejoba, gbogbo agbara Alaafin tabi oba yoowu ko si ju ile re nikan lo. Niluu re paapaa, ajele oyinbo lagbara ju u lo, nigba to je awon ni won n shejoba.

Ohun ti opo eeyan ko she gbo nipa oye naa mo ree, nitori bo tile je pe leyin igba naa, awon Alaafin merin mi-in lo ti je: Alaafin Adeyemi Alowolodu to waja, Agogooja to je leyin tire, Shiyanbola Onikepe Oladigbolu ati Adeniran Adeyemi Keji. Ninu awon oba mereerin yii, ko si eyi to tun dabaa Aare Ona Kakanfo mo, nigba ti ko si oju ogun to fee ran an lo. Bo tile je pe awon omo Yoruba wa to loruko daadaa bii Herbert Macaulay, Kitoye Ajasa, Eric Moore, Shapara Williams pelu awon mi-in ti won mowe, ti won n ba awon oyinbo shishe, ti won si je ojulowo Yoruba, ko senikan to fi ipo aare lo won, nitori ko si ohun ti won o fi i she. Eyi ko je ki awon omo Yoruba mo ipo naa ati bo she she pataki to laye atijo, elomi-in o si gbo oruko naa ri, afi ninu iwe awon onpitan, ati ninu owe awon Yoruba bii aare n pe o o n d'Ifa, bi Ifa re fore bi aare ko ba fore nko.

Afi lojiji ti awon oloshelu de, ti wahala si bere, ti won deede so pe won yoo fi Samuel Ladoke Akintola je Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, leyin odun metalelaaadorun-un (93) ti Latoosa ti je oye naa gbeyin.

Ki lo waa de ti Akintola loun yoo di aare ile Yoruba? E ka a ninu Iwe Iroyin lose to n bo.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:35:44 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo:
Yoruba Greetings, (Middle) Names In Yoruba Language With Titles Of Obas (Kings)


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

"Itan Bi Ladoke Akintola Se Di Aare-Ona-Kakanfo Ile Yoruba" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com