Gbagede Yoruba
 

 
Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So
 
Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So

Laaro kutu ojo Eti tii se Fraide ana ni iroyin naa jade sita Aare teleri l'orile-ede Zimbabwe, Robert Mugabe ti jade laye. Kayeefi, ati pe lojiji niroyin iku naa ba gbogbo agbaye.

Ohun ta a gbo ni pe osibitu kan lorile-ede Singapore ni Robert Mugabe wa lati bi osu meloo kan seyin nibi to ti n gba itoju, latari aisan ojo ogbo ti won loo koluu, to si je pe nibe lo gba jade laye leni odun marundinlogorun (95years).

Lati odun 1980 lo ti n tuko orileede Zimbabwe titi wo odun 2017 nigba ti igbakeji re ye aga mo nidi pelu atileyin ileese ologun.

Adanu nla n'iku Rubert Mugabe je, Olusegun Obasanjo

Aare orileede Naijiria nigbakan ri, Olusegun Obasanjo ti so pe, iku aare Zimbabwe ana, Robert Mugabe je adanu nla fun gbogbo ile adulawo lapapo.

O salaye pe Robert Mugabe je ajijagbara ti o mo pataki ki eeyan ja fun ominira.

Aare Obasanjo wa kedun iku aare ana ohun, o si tun so pe yoo soro lati ri eni ti yoo lee di alafo ipo ti oloogbe naa dimu nile adulawo gege ajijagbara.

"Mugabe fi ìgboya dáábo bo ile Áfíríka lowo ìmúnisìn

Baa ku laa dere, eeyan ko sunwon laaye.

Awon olori orileede Lagbaye ti n sedaro akeegbe won, Robert Mugabe to siwo ise ni aaro ojo Eti.

Mugabe fi ara re jin fun ironilagba oro aje ati oselu - Aare Naijiria

Nigba to n daro pelu orileede Zimbabwe lori ipapoda akoni asaaju naa, aare ile Naijiria, Muhammadu Buhari ni oloogbe naa je ajijagbara to ja fitafita fun ominira orileede ohun, to si fi opo igba aye re sin omoniyan.

Ninu atejade kan ti amugbalegbe fun eto iroyin re, Femi Adesina fisita, Buhari ni opo ifiraenijin ti Mugabe se, paapa nidi ijijagbara fun ironilagbara awon eeyan re leka oselu ati oro aje ni iran yii ati eyi to n bo ko ni gbagbe laalae.

Buhari wa gbadura pe ki Olorun de ile fun akoni naa, ko si tun tu awon ebi re ninu lori isele adanu nla yii.

Awujo agbaye yoo maa ranti Mugabe gege bii 'eni to ni igboya' - Aare Kenya

Bakan naa ni aare orileede Kenya ti se apejuwe Robert Mugabe gege bii "agba awujo, ajafun ominira orileede ati ololufe ile adulawo to se ojuse ti ko kere lati mu atunse ba ife ile adulawo"

"A maa ranti aare Mugabe gege bii onigboya eda, ti kii beru lati ja fun ohunkohun to ba nigbagbo ninu re, koda araye koo baa lodi si ero naa."

Afirika ti padanu okan lara awon akinkanju asaaju - Aare Tanzania

Loju opo Twitter tie, aare orileede Tanzania, John Mugufuli ti sedaro lede Swahili pe "Ile Afirika ti padanu okan lara awon akinkanju asaaju, eni to tako iwa imunisin lati ipase awon igbese re."

Mugabe fi emi aiberu daabo bo ile Afirika - Aare Zambia

Ko tan sibe, aare ile Zambia Edgar Lungu naa ti kede pe "A maa ranti Mugabe fun bo se 'fi emi aisiberu daabo bo ile Afirika'."

Loju opo Twitter re, o ni "oludasile orileede Zimbabwe ati ololufe ile adulawo" naa ni oruko re ko ni pare ninu itan ile Afirika."

Awon 'ogún burúkú' tí Mugabe fi síle sì wa síbe - Olóselú alátako

Opo awon eeyan lagbo oselu lorileede Zimbabwe, awon olori orileede lagbaye ati awon eekanlu lawujo agbaye ti n so ohun ti won mo nipa Robert Mugabe.

Eyi to ya ni lenu julo ni bi awon eeyan kan se n soro ti ko to nipa oloogbe naa.

Akowe foro ile okeere ni ilu Oba, United Kindom, Emily Thornberry kede pe oun ko lee sun ekun kankan nitori pe Mugabe jade laye.

"O gba akoso orileede to si n se opo ileri...sugbon nigba to ya lo sina patapata, mo si ro pe o seranwo lati ba anfaani ti orileede re ni lojo iwaju lati de ibi giga je."

'Mugabe kuro lati ajijagbara bo si afiyajeni'

Bakan naa ni akojo iroyin kan ni Mugabe ba oro aje awon alawo funfun je ni orileede Zimbabwe nitori pe won ri owo mu ni orileede olora naa.

Iroyin naa n se ni iroyin ayo gba gbogbo orileede Zimbabwe kan nigba ti won fi tipa ye aga mo Mugabe nidi.

'Ogun buruku' ti Mugabe fi sile si wa sibe - Oloselu alatako

David Coltart tii se oloselu alatako latinu egbe oselu MDC lorileede Zimbabwe ti kede pe gbogbo omo orileede Zimbabwe ni ko ni gbagbe Mugabe nitori iwa ipa ati iwa ajebanu to fi sile nile naa.

Coltart, ti Mugabe so ni suna 'ota orileede' , ks soju opo Twitter re pe won ko ni gbagbe oloogbe naa pe ko seese ki eeyan fi oju fo opo asise oloogbe naa lasiko to wa lori oye.

Opo ìtan tí Robert Mugabe ko nígba aye re ree:

Nigba ti Robert Mugabe n se abemi loke eepe, o ko oniruuru itan manigbagbe to koja ero eda,

Bi o tile je pe omo atapata dide ni Mugabe, ti baba re si je Kafinta, sibe ko je ki igbe aye mekunnu yii di oun lowo lati de ibi giga laye.

Robert Mugabe, tii se oluko ni ibere pepe aye re, ni oju re ri mabo lowo awon oyinbo amusin ko to di pe orileede Zimbabwe, taa mo si Rodesia tele, gba ominira.

Die ree lara awon koko ohun ti Mugabe gbe ile aye se:

1924: Ojo ti a bi

Leyin e yi, o di oluko
1964: Ijoba orileede Rhode ju si ewon
1980: O bori ninu idibo to saaju ominira orileede naa
1996: Mugabe fe iyawo re, Grace Marufu
2000: O kuna ninu idibo beeni tabi beeko, awon omo ogun re (pro-Mugabe militias) se ikolu si oko awon eniyan alwo funfun ati egbe alatako lorileede naa
2008: O se ipo keji ninu idibo to gbe Tsvangirai wole ni ipele akoko, amo ti Tsvangirai so wi pe oun ko se mo leyin ikolu si awon alatileyin re
2009: Mugabe bura wole fun Tsvangirai gege bi Olootu ile naa laarin oro aje to denukole fun odun merin
2017: O kowe lo gbe ile re fun Igbakeji re,Emmerson Mnangagwa, eleyii to faye sile fun iyawo re, Grace lati bo si ipo
2017 November: Ile-ise ologun fi ipa gba ipo lowo re
2019 September: Robert Mugabe dagbere fun aye pe o digbose.

"Robert Mugabe, a ko lee gbagbe ìtan rere tó ko ní Zimbabwe"

Bi ode ba ku, ode naa lo n se oro leyin ode.

Ni kete ti iroyin iku aare ana lorileede Zimbabwe gba orileede agbaye kan, ni opo eeyan ti n se idaro iku re.

Niwon igba to si je pe onikangun ni ikangun, aare to wa lori oye lowo-lowo bayii, Emmerson Mnangagwa, lasiko to n kede iku oga re tele naa fi tedun tedun so bi iku Mugabe ti kaa lara to.

Emmerson Mnangagwa, eni to daro loju opo Twitter re salaye pe "akoni fun eto ijijagbara ati alawo dudu to nife ile re tokan-tokan ni Robert Mugabe nigba aye re.

O ni Mugabe fi gbogbo aye re ja fun ominira ati eto ironilagbara awon eeyan re ni, ti orileede Zimbabwe ati ile Afirika lapapo, ko si lee gbagbe ipa manigbagbe to ko ninu itan.

Bee ba gbagbe, Emmerson Mnangagwa lo fi tipa gba ipo aare lowo Robert Mugabe pelu atileyin awon ologun losu Kokanla odun 2017.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:28:33 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· EsinIslam Media Yoruba
· Die sii Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere:
Oye Okere Tilu Saki, Ile-ejo Ni Mogaji Ko Gbodo Gbe Igbese Kankan Bayii


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Koko Irohin Ati Olori Atoka/Itan/Ibeere

"Awon Aare Agbaye N Se Idaro Iku Robert Mugabe, E Gbo Nnkan Ti Obasanjo So" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com