Gbagede Yoruba
 

 
Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbes
 
Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbesan L'ara South Africa

awon omo Naìjra n ìpnle Eko ti gba ìgboro lti koju ìkora eya miran ti awon South Africa ń se fn awon omo Naìjra.

Ile ìtaja ìgbalde Shoprite t agbegbe Lekki n omobinrin kan ti gbe ìwe ilewo lti bu enu ate lu ìw akolu ti awon South Africa n se si awon omo Naìjra.

awon mran tll ń kigbe pe ki won dn sun ile itaja na ljùna ati ranse pada s awon enìyan South Africa gege bi esan.

T e o b gbagbe awon omo orle-ede South Africa t ń ko soobu ti won sì ń pa awon omo Naìjra ni orile-ede won.

Ìroyìn so pe opo awon t ń gba ìgboro l ti padnù awon eb won nn wahal t awon ar South Africa ń dsle.

E fi olopa wa sarin olopa yn n South Africa fn aabo ajejì - ìjoba Najra beere

Ijoba ile Naijiria ti kesi ijoba ile South Africa pe ko yara tete setan lati san owo gba ma binu fun awon omo Naijiria to fara kaasa opo ikolu lati owo awon omo orileede re.

Minisita foro ile okeere lorileede Naijiria, Gofferey Onyeama lo te pepe ibeere naa siwaju asoju ijoba ile South Africa to ranse pe laaro oni.

Bakan naa lo koro oju si ijoba ile South Africa pe o moomo n fi oro titi owo bo iwe adehun igboraeniye laarin orileede mejeeji fale.

Iwe igboraeniye ohun lo wa lati wa ojutu si bi awon omo ile South Africa se maa n kolu awon ajeji to wa lorileede won.

Bakan naa tun ni ijoba Naijiria n beere lowo ile South Africa pe ko fi awon olopa Naijiria sinu awon olopa ile South Africa, ki won si tun wa lara awon asoju ile wa ni South Africa.

"B ebe ko b dekun ìkolù South Africa, e gbe ileese asoj re n Najra tìpa"

Enu lasan ko le dekun oro bi awon omo bibi orileede South Afrika se n kolu awon ajeji, taa mo si Xenophobia, eyi to ti wa n di lemo-lemo bayii, ayafi ki ijoba Naijiria gbe igbese to lagbara lori re.

Eyi ni ero asoju ile Naijiria sorileede Uganda tele ri, Ambassador Omolade Oluwateru, eni to tun ti je igbakeji gomina tele nipinle Ondo.

E gbo Oluwateru siwaju si:

Ambassador Oluwateru daba yi gege bii lona abayo nigba to n ba BBC Yoruba soro, nipa ariwo to gbode lori bi awon omo orileede South Africa se n deye si awon omo Naijiria.

Oluwateru ni o seni laanu pe orileede South Afrka ti Naijiria ti se loore to po, ni yoo ma wa fi eyin obe je Naijiria nisu.

O ni bi owoja ideyesi yii ti se wa peleke bayi, ijoba Naijiria gbodo gbe igbese to le, ki South Afrika ba le mo pe ko fi owo yepere mu emi awon omo ile re leyin odi.

"Leyin ti Naijiria ba parowa si South Afrika ti won ko gbo, ohun to ye ni ki won pase ki asoju Naijiria ni South Afrika pada wa sile ni kiakia"

O tun salaye pe ti igbese yii ba ko ti ko dekun oro naa, ki Naijiria ti ileese asoju South Afrika to wa ni Naijiria pa, ki won si da asoju won pada si ile won.

Nigba ti a beere boya Naijiria le gbe awon omo ile re to wa ni South Afrika pada wa sile, Otunba Oluwateru ni o seese sugbon kii se gbogbo eeyan naa ni yoo fe pada wa sile.

"Awon miran le e ni ise ti won n se nibe ati pe, ti a ba gbe won pada, ki ni won fe maa wa se nile? Eko gbigbona loro yi, o gba ki a fi suuru to"

Kini Ijoba Naijiria ti se?

Lowolowo bayii, ijoba orileede Naijiria ti ranse ke si asoju ijoba ile South Africa to wa ni naijiria si ibi ipade kan.

Bakan naa, Minisita foro ile Okeere, Geoffrey Onyeama loju opo Twitter re, ti wa benu ate lu isele yii, to si ni Naijiria yoo gbe igbese to peye lori oro naa.

O ni o to ge bi won ti se n dana sun awon ile itaja omo Naijiria lorileede South Afrika.

Sugbon opo Naijiria lo n woye pe ijoba orileede yii ko tii se ohun to ye, to ba si fe dekun ikolu yii, o gbodo san sokoto re ko le ni.

"A ko n ra oja South Africa mo, a gbesan or t won ń d wa - Omo Najra frg"

Igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere la tii wo o, o wa to asiko bayi ki ijoba Naijiria wa woroko fi sada lori oro ikolu South Afrika sawon omo Naijiria to n di lemolemo bayii.

Eyi ni ero okan opo omo Naijiria loju opo Twitter lori iwa idojule ti awon omo South Afrika n hu si awon omo Naijiria nile won.

Kaakiri oju iwe iroyin ati loju ayelujara ni iroyin ati fonran fidio orisirisi ti n se afihan bi won ti se n doju ija ko awon omo Naijiria ati omo ile Afrika miran.

Idunkoko awon omo South Afrika mo awon omo orileede Afrika miran lenu ojo meta yii je ohun to n fowo kan opo eeyan lemi.

Lara awon to ti ke gbajare yii la ti ri gbajugbaja soro soro nii, Daddy Freeze, ti o ni oun ko ni ra oja kankan to ba je ti orileede South Afrika mo.

Arabinrin Faithe marere da lohun pada ti o si daruko awon ile itaja ti o je ti South Afrika, to ye ki awon omo Naijiria deye si.

Ideyesi awon omo ile Afrika lati owo awon omo South Afrika ko sese ma waye.

Lopo igba ni awon omo Naijiria ti ma n farakasa isele yii ,ti o si ti ma n mu ki awon eeyan kesi ijoba awon orileede mejeeji lati mu opin ba iru iwa yii.

Pupo awon ileese South Afrika lo ti peka de Naijiria ti won si n ri ere tabua lodo awon eeyan Naijiria.

Eyi wa lara ohun ti o mu ki awon eeyan Naijiria ma faraya, bi awon omo South Afrika ko ti se ni emi amumora fun awon eeyan miran.

bbc

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:13:14 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin:
Buhari Omo Musa Sa Kuro Nibi Ayeye Igbeyawo Saidi Osupa: Lehin Ti Alfa Muri Fun


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Isele Agbaiye Musulumi Ati Irohin Esin

"Xenophobia (Ikorira-Ajeji) Attack: Awon Omo Naijiria Ti Yari Pe Awon Naa Yo Gbes" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com