Gbagede Yoruba
 

 
Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku
 
Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku

Agutan ti ko ri omo re mo, eran fohun, o ni, 'Nnkan n be!' Nnkan n be loooto fun Naijiria, nitori nigba ti iya nla ba gbe ni sanle, keekeeke a si maa gori eni. Iya nla ti gbe Naijiria sanle bayii, awon keekeeke si n gun ori Naijiria, orile-ede ti gbogbo aye n gbe gege laarin odun 1960 titi wo 1980 waa di orile-ede yeye, orile-ede ti kaluku fi n se eleya kaakiri. Igba kan ti wa to je ko si ohun ti won yoo se ni gbogbo ile Afrika pata, ti Naijiria ko ba ti da si i, ko seni ti yoo bere re, enu Naijiria nikan ni ase wa nigba yen.

Sugbon ohun to n sele ni orile-ede South Afrika bayii ti fihan pe Naijiria ati awon omo orile-ede yii ko je nnkan kan mo nibikibi, eni yeye lasan lawon eeyan orile-ede agbaye gbogbo ka wa si. Ni South Afrika lose to koja, eyin naa kuku ti ka a, e si ti ri i bi awon omo orile-ede ohun ti tu awon omo Naijiria sihooho, ti won n na won, ti won n wo won nile, ti won n dana sun won, ti won si n ko soobu ati eru won, ti won n fo moto won tuu tuu, to si je gbogbo omo Naijiria ti won ba ti ri loju ona ni won n se lese. Oro naa buru jai, koda, won o gbodo se eranko to bi won ti n se wa.

Ko si alaye kan tijoba tabi enikeni le se, ikoriira fun awon omo Naijiria lo fa ohun ti won n se yii, iwa pe awon eeyan to wa ni South Afrika ko fe eya to wa ni Naijiria ni. Won n pa awon omo Naijiria yii nitori won ri se ju won lo, won n na won nitori won lowo, won si lola ju won lo. Kin ni won yoo tile so, sebi awon olopaa wa nibe ti won duro ti won n woran awon ti won n fiya je awon omo Naijiria yii, to si je nibi ti oju ba ti pofiri, awon naa yoo da si i lati fiya je omo Naijiria ti won ba ri.

Bi won se da wahala bole to, ijoba orile-ede South Afrika ko reni kan mu ninu won, nitori ijoba naa ko fee se kinni kan, 'Olorun mu won' lawon naa n wi, won si fe ohun to n sele si Naijiria daadaa. Awon olori orile-ede won, ati awon asaaju won to ku, lo jebi saa o, nitori won o salaye awon oore nla nla, oore manigbagbe, ti Naijiria ti se fun orile-ede naa fun awon omo won to n kiri oju titi yii ni.

Bo ba je won wa salaye fun won ni, awon omo wonyi yoo mo pe bi ko ba si ti Naijiria ni, ipo eru lawon iba wa ni orile-ede won naa titi doni. Naijiria lo saaju gbogbo ile adulawo to ku pata, ti won ri i pe won gba South Afrika kuro lowo awon oyinbo, won si da ijoba ile naa pada si owo awon eeyan dudu. Awon oyinbo ti gba ile won, won si ti so won di eru lorile-ede won, sugbon nigba ti ijoba Naijiria tese bo oro naa, latori awon Gowon titi dori awon Obasanjo, wahala ba awon oyinbo South Afrika, won si fi tipatipa ati itiju nla gbe ijoba pada sowo awon ti won ni ile won.

Tele, awon omo South Afrika ki i lo sileewe tawon oyinbo yii ba n lo, won o gbodo wo moto kan naa pelu omo oyinbo, won ko gbodo duro jeun nibi kan naa pelu won, won o si gbodo lo si osibitu tawon omo oyinbo ba n lo, Naijiria lo saaju awon ero agbaye to ku, ni won ba gba ile South Afrika pada, nigba to je ile awon eeyan dudu ni, alejo lawon oyinbo yii, won waa sowo nibe ni, ni won ba taku pe awon ko lo mo.

Ogede ti waa wo koko ye tan bayii, o ti di igi buruku, Naijiria gba South Afrika loko eru tan, awon omo won ko pada mo itan mo, omo Naijiria lo ku ti won fee maa pa je. Eni ba fi ibi soloore, iya ni yoo je ku, Naijiria ko ni i maa ba bayii lo titi, ojo kan n bo ti oro yoo yipada, awon omo South Afrika naa yoo gbesan ohun ti won n se.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 07:08:40 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo:
Yoruba Greetings, (Middle) Names In Yoruba Language With Titles Of Obas (Kings)


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

"Eni Ba Fibi Soloore, Iya Ni Yoo Je Ku" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com