Gbagede Yoruba
 

 
L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo
 
Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo Florence Babashola

L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo

Awon marun-un ti igbagbo wa pe won je omo egbe okunkun toruko won n je Eiye Confraternity, Nasirudeen Jamiu, eni odun metadinlogbon, Ganiyu Saheed, eni odun meeedogbon, Adebisi Idris, eni odun merinlelogun, Adeoye Sodiq eni odun merinlelogun ati Kasali Afeez toun naa je omo odun merinlelogun ti won fesun kan pe won pa Monsuru Lawal ni won ti foju bale-ejo Majisreeti ilu Oshogbo bayii.

Esun meta otooto to ni i she pelu gbigbimo-po huwa buburu, ipaniyan ati jije omo egbe okunkun ni won fi kan awon olujejo yii.

Agbefoba, Inspekito Elisha Oluwashegun, shalaye pe awon olujejo ohun pelu awon mi-in ti owo ko ti i te ni won huwa ohun lagbegbe Isale-Oshun, lojo kesan-an, oshu keje, odun yii.

Oluwashegun so siwaju pe gbogbo esun ti won fi kan awon olujejo ni alakale ijiya won wa labala ikerinlelogota (64) ati okooleleeedegbeta o din merin (516) ofin iwa odaran ti odun 2002 tipinle Oshun n lo.

Nigba to n ka idajo re, Onidaajo A.O. Ajanaku pashe pe ki agbefoba fi eda iwe esun naa ranshe si ileeshe eto idajo ipinle Oshun fun imoran to to lori e.

O waa pashe pe ki won ko awon olujejo naa satimole ilu Ilesha titi di ojo ketalelogun, oshu kewaa, odun yii, ti ile-ejo yoo tun menuba oro won.

Ishe oko wiwa lawon eeyan mo okunrin kan, Emmanuel John, mo ni Badagry, nipinle Eko. Sugbon lojo kejila, oshu kefa, odun yii, tawon eeyan n shayeye demokiresi ni Naijiria, ibon oloju meji lawon olopaa ba lowo Emmanuel lai niwee ashe, ohun ti won mu un fun niyen.

Eni odun mejilelogbon ni Emmanuel towo ba yii, oju ona marose Badagry ni won ti mu un pelu ibon ilewo oloju meji naa. Yato sibon ohun, ota ibon meji tun wa ninu apo e, bee ko si lansensi kankan lowo dereba to n wako yii, ko si si idi kankan fun un lati maa gbe ibon rin bi won she ba a lowo e.

Esun ti ko le shalaye kankan nipa e yii naa lawon olopaa ka si i lese ni kootu Majisireeti to wa n'Ikeja, nibi ti won gbe e wa l'Ojoruu to koja yii, ti won ti ni ko waa shalaye idi to fi n gbe ibon rin lojumomo lai ni iwe ashe fun un.

Adajo Adegun ni bi ko ba ni ero ibi lokan, tabi ko si je pe boju-boju lasan nishe awako to loun n she yii, Emmanuel ko ni i maa gbe ibon rin kiri ilu, nigba to je ofin ile wa ko faaye gba iru e. Nidii eyi, ko gba ipe olujejo yii, alaye re kankan ko si shishe pelu.

Oju ese lo pashe pe ki won maa gbe Emmanuel lo sogba ewon Kirikiri, ibe ni yoo wa titi di ojo kesan-an, oshu yii, nigba ti igbejo re yoo maa tesiwaju.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 06:52:31 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo:
Yoruba Greetings, (Middle) Names In Yoruba Language With Titles Of Obas (Kings)


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo

"L'Oshogbo, Awon Omo Egbe Okunkun Ti Won Fesun Ipaniyan Kan Foju Bale-ejo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com