Gbagede Yoruba
 

 
Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re

Senken bayii lowo olopaa ipinle Akwa Ibom te Baale ile kan, Idorenyin Essien, eni odun marundinlogoji ti won loo dana sun omo re latari esun to fi kan omo naa pe o ji owo oun, eedegbeta naira gbe.

Bo tile je pe "ise esu ni" loro ebe to n tenu Essien jade, sugbon sibe, epe rabande lawon eeyan n gbe okunrin naa se lori iwa odaju to hu naa, ti won si n be awon olopaa pe ki won rii daju pe won ran an lo sewon gbere.

Agbegbe Afia Nsit to wa nijoba ibile Eket nisele naa ti waye lojo Fraide ose to koja yi, sugbon to je pe ana Tuside lawon olopaa fidi isele naa mule leyin towo palaba Essien segi.

Alukoro ileese olopaa ipinle naa, Odiko Macdon nigba to n fidi oro naa mule bu enu ate lu iwa ti Essien hu naa, to si lawon ko ni i foju aanu wo rara, ati pe gbogbo ona ti ile ejo yoo fi gbe idajo ododo kale lawon yoo gba nitori pe elese kan ko nii lo lai jiya.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe omo naa ta a foruko bo lasiri loo ji owo eedegbeta naira, to si loo fi ra ounje latari ebi to n pa a, tori ti won so pe iya ni baba re fi n je, kii sii fun lounje lasiko. Bi Essien se gbo ni won loo lo san owo naa.

Bo si se pada sile lo ran omo re yin ni karosiini, peluu idunnu la gbo pe omo naa fi sare loo ra lai mo pe baba re ni erongba buruku lokan sii. Bo se pada de, ni won ni Essien fi okun de omo naa, to si gbe e siwaju ita, nibi to ti da karosiini naa si i lara, to si ju ina sii.

Awon ara adugbo to wa nitosi la gbo pe won doola emi omo naa la ti gbe e lo si osibitu, sugbon o seni laanu pe oju ona lomo naa dake sii.

Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu: Won Fun Iyaale Ile Lorun Pa Nile Itura

Odaju Abiyamo Re o: Baba Lu Omo Re, Omodun Meta Nilukilu

Bo tile je pe a ko ti mo nnkan to shele laarin baba ati omo re, omodun meta, to mu ki baba naa daa dubule, to si ko patie bo o bii maalu to gbojo iku.

Ilu Ogbomosho nipinle Oyo nishele naa ti waye lojo Satide to koja yi.

A gbo pe baba naa ati iyawo to sheshe fe ni won jo dawo bo omodun meta naa, to si je pe awon eleyinju aanu ni won gba omo naa sile.

Foto omo naa le n wo yii.

Baale Ile Da Aisidi Siyawo Atowon Omo Re Lara, Lo Baa Na Papa Bora: Ile To Wo L'ekoo, Won Ni Kii Shoju Lasan

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 06:43:22 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo:
Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo

"Nitori Eedegbeta (500) Naira, Odaju Baba Sun Omo Re" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com