O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo
O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo Egbe OOkunkun One Million Boys L'ekoo
Ofin tuntun bayii ti orile-ede South Afrika gbe jade bayii ni pe ko si omo Niajiria kan shosho ti yoo wo ilu won lai gba iwe irinna, ati pe awon omo orile-ede Ghana yoo peluu awon ti yoo maa je anfaani lati wo ilu won nigba to ba wu won lai gba iwe irinna.
Be o ba gbagbe, ati pe fawon to ba mo bi eto oro aje South Afrika she n lo, orile-ede Naijiria ni won ti n jere to poju lagbaye, to si tun je pe ko si orile-ede naa lagbaye ti won le fowo soya pe orile-ede Naijiria ko ni won ti n je ere to poju.
Orile-ede meje ni awon to n ri soro irinna lorile-ede South Afrika, iyen South Africa's Department of Home Affairs gbe jade pe awon ti fun won ni anfaani lati maa wo ilu won lai gba iwe irinna lasiko to ba wu won, to si je pe Naijiria ko si ninu won.
Minisita fun eka naa, Aaron Motsoaledi lo kede oro naa sita, to si tun je ko di mimo pe irin ajo afe lawon tun fe maa fi pawo wole sapo ijoba won bayii, tori pe nnkan to gbe owo lori kaakiri agbaye lasiko yi ni.
OWO TE AWON OMO EGBE OKUNKUN ONE MILION BOYS L'EKOO
Orin 'ope ye o Baba' lawon eeyan mu senu nipinle Ekoo lana an, iyen nijoba ibile Ojo, nigba towo palaba awon mejo kan segi nibi ti won ti fee gbawon eeyan wole sinu egbe okunkun.
Ojule keedogun, adugbo Alado, Shibiri lowo ti te won nigba ti won so pe Yusuf Abu, omo ogun odun lo fee gbawon eeyan wole sinu egbe okunkun ti won pe ni One Milion Boys naa.
Awon towo te naa ni Sunday Gabriel, omo ogun odun; Rilwan Dauda, omodun mejidinlogun; Mohammed Sikiru, omodun metalelogun; Oladimeji Abayomi, omodun mejidinlogun; Rasheed Alabi, omo ogun odun; Habeeb Idowu, omodun mejidinlogun; Bisola Olaiya, omodun mejidinlogunati Hawawu Hazzan toun je omodun mokandinlogun.
WON DANA SUN ADIGUNJALE L'AKAWA IBOM NITA GBANGBA
Bo tile je pe a ko tii le fidi nnkan ti okunrin kan ti won dana sun lopopona Essien, agbegbe Ikot Ekpene nipinle Akwa Ibom ji gbe mule, sugbon sibe, iyalenu nla lo je fun opo awon o rin si asiko nigba ti ju ina omo orara sii lara, to si jona gburugburu.
Gege bi a she gbo, won ni awon kan ni won n le okunrin naa bo, ko too di pe awon kan da a duro, ti won si bere sii luu, ko too di pe won ju taya moto sii lorun, ti won si dana sun un.
Pupo awon to rii ni won n ba a kaanu, nigba to n bebe pe ki won foju aanu wo oun, sugbon ti won ko ti e gbo, afigba ti won rii pe emi jabo lara re.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Sunday, September 01 @ 03:11:23 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
"O Tan! South Africa Lawon Omo Naijia Ko Le Wo Iluwon L'ofe: Owo Te Awon Omo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ