O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle
O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle Ogun Teleri Ku Lokiji
Titi dasiko ti a ko iroyin yi tan, lawon eeyan shi n fi oro ibanikedun ranshe si Komishana foro epo robi ati idagbasoke, iyen Oil Producing Area Development Commission (ASOPADEC) nipinle Abia, Onorebu Adeile Ekeke.
Ojo Sannde to koja ni Onorebu Ekeke padanu iyawo e ati omo meji sinu ijamba moto lopopona Enugu-Okigwe, lasiko ti won n rin irin ajo, ko too di pe ijamba naa waye lojiji.
Loju ese ni gbogbo won ti dagbere faye, to si mu kawon eeyan kawo mori.
Awon tishele naa shoju won la gbo pe won gbe won lo si moshuari, to si je pe ana tii she Tuside ni won sin won.
IGBAKEJI GOMINA IPINLE OGUN TELERI KU LOJIJI
Iyalenu loro iku to wole mu igbakeji gomina teleri nipinle Ogun, Alaaji Abdul Rafiu Ogunleye shi n je fawon omo ipinle naa, paapaaawon molebi re titi dasiko yi.
Bo tile je pe loju ese ni won ti fi eeru fun eer, erupe fun erupe, sugbon ohun ta a gbo ni pe aaro ana tii she ojo Aje ni Alaaji Ogunleye ki aye pe o digboshe leni odun mokandinlogorin (79years) ni osibitu kan to wa ni Itele-Ijebu.
Fawon ti ko ba mo Ogunleye, odun 1992 si odun 1993 ni Alaaji Ogunleye fi je igbakeji gomina ipinle Ogun nigba naa, iyen Oloye Olushegun Oshoba.
Ni bayii, Gomina ipinle Ogun, Omoba Dapo Abiodun nigba to n kanminu lori iku Ogunleye, o shapejuwe re gege bi olufokansin ati ashiwaju toooto, to si tun ba molebi re kedun.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Sunday, September 01 @ 03:07:18 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
"O Ma She o!, Komishana Padanu Iya Ati Omo Meji Lojo Kan Shosho: Igbakeji Ipinle " | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ