Owo Te Wahab Nibi To n Ti n Se'Kinni' Fomo Odun Mewaa Legbee Ogiri
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta
Owo Te Wahab Nibi To n Ti n Se'Kinni' Fomo Odun Mewaa Legbee Ogiri
Bi won ba n wa oniranu aye atorun, omokunrin eni ogun odun kan ti won n pe ni Wahab Abdul Azeez lo ye ki won mu pelu iwa idoti to hu, to tun fi ra awon ebi e lara.
Lose to koja lowo te Wahab ni koro ile kan ti won ko ti i ko pari, nibi to ti n ba omobinrin eni odun mewaa kan lo po. Adugbo kan ti won n pe ni 'Sparkling Estate', ni Isheri Olofin, nisele naa ti waye.Gege bi Omooba Muyiwa Adejobi to je agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun se wi, iya omo naa ran an nise ni ti Wahab fi tan an wo koro ile akopati naa, to si bere si i ba a sun lori iduro.
Iya omo yii la gbo pe o loo fejo sun, eyi to mu kawon olopaa mu Wahab, toun naa si jewo pe loooto loun se kinni fomo naa, sugbon esu lo tan oun, ati pe oun ti se e tan ki oju oun too ja a.
Ni bayii, komisanna olopaa nipinle Ogun, Abdul Majid Ali, ti pase fun DPO ti Ojodu lati fi afurasi naa ranse si eka to n ri si lilo awon omo nilokulo to wa ni olu-ileese won ni Eleweran, niluu Abeokuta, fun iwadii si i.
Bee lo tun gba gbogbo awon to nile akopati nipinle Ogun nimoran pe ki won tete wa nnkan se lori e, ki won ma je kawon eni ibi maa lo awon agbegbe naa fun ise ibi won.Bakan naa lo tun gba awon araalu nimoran lati fowo sowo po pelu awon olopaa lati bori awon odaran to wa lagbegbe won.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 21:44:01 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
"Owo Te Wahab Nibi To n Ti n Se'Kinni' Fomo Odun Mewaa Legbee Ogiri" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ