Iku okunrin awako ero kan to n je Mumini niluu Lalupon, nipinle Oyo, ti ko itiju nla ba awon ebi ati ojulumo re bayii pelu bi okiki ti se kan kiri pe aisan ibalopo kan ti won n pe ni magun ni baba naa lu.
Lara iyawo baba oloye kan niluu Iyana-Offa ni won ni Mumini ti lu magun, sugbon ko si eni ti i ba mo pe magun lokunrin awako yii lu bi ko ba se pe oun funra re fi enu ara e so o nitori ojo keje to kan ijangbon ohun ni kinni naa ja si iku fun un.
Awon olugbe ilu Iyana-Offa fidi e mule pe o pe ti Mumini, eni tawon eeyan tun mo si Gidado pelu iyawo baba oloye naa to n je Iya Ade ti jo n se wolewode ikoko. Bo si tile je pe oko-iyawo ko mo si ibasepo yii, sibe, ara fu baba naa nitori irin tiyawo e maa n rin lopo igba ki i ye e, bee lobinrin naa ki i gba ko ba a lajosepo ninu ile.
Gege b'Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ni gbogbo igba ti Baba Oloye, eni ti a foruko bo lasiiri ba fi oorun sisun lo iyawo e lobinrin ti ko ju eni ogoji odun lo naa yoo so pe oun ko raaye tie nitori o ti dagba ju. Eyi lo mu ki ara fu baba naa to fi le magun si i lara, sugbon tobinrin naa ko mo.
Won ni kete ti Gidado lu pakute iku ti won de sara obinrin yii ni aisan ti kolu u, ti ko le jeun mo, to si bere si i sare ru hangogo ni iseju iseju. Sugbon nise lo n pa kinni naa mora, to si rora n toju ara e labele fodidi ose kan gbako. Nigba ti kinni ohun fee gbemi e lo jewo fawon ebi e pe magun toun lu lara iyawo oloye lo n pa oun ku lo. Lojo to soro ohun gan-an naa lo si jade laye.
Okunrin olokada kan to ba akoroyin wa soro lori isele yii salaye pe magun ti ki i tete e paayan ni Baba Oloye fi sara iyawo e, ati pe omi-in tile wa to maa n to ojo kerinla lara okunrin to ba lu u ko too pa oluware.
Gege bo se so, ''Nigba ti Gidado ku tawon eeyan bi Baba Oloye leere pe se loooto lo le iyawo e ni magun, o ni ko sohun to jo o.'' Won ni Gidado to je eni odun marundinlaaadota to n na Ibadan si Iyana-Offa lo si Lalupon ki i gbadun iyawo e ninu ile, nitori aajin oru lobinrin naa feran lati maa wole, bee ni ile ki i mo tan ti yoo ti jade nile. Ojo Aiku, Sannde, to lo lohun-un lo dagbere faye, won si sinku e siluu e ni Lalupon, nijoba ibile Lagelu, nipinle Oyo.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 21:36:13 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ