Gbagede Yoruba
 

 
Imeh Ha Sowo Olopaa L'Ekoo, Aburo Iyawo e Lo Se Kinni un Fun
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga Lati Owo Oluyinka Soyemi

Imeh Ha Sowo Olopaa L'Ekoo, Aburo Iyawo e Lo Se Kinni un Fun

Iwadiigidi lo n lo lowo bayii lori iwa ainitiju ti afurasi odaran eni odun merindinlogoji kan, Imeh Akpan, hu latari bo se ba aburo iyawo re lasepo ni tipa. Ose to koja ni ileese olopaa ipinle Eko safihan okunrin naa lolu-ileese won to wa n'Ikeja, nibi to ti n seju pakopako nigba to n so ohun to ri lobe to fi waro owo.

Iwadii Iwe Iroyin Yoruba fi han pe agbegbe Obalende ni afurasi ohun n gbe pelu iyawo re, omo to fipa ba lo po ta a foruko bo lasiiri yii si wa lodo won. Agbo pe lati kekere lomo naa ti n gbe pelu molebi naa, aburo iyawo ni, sugbon o jinna si egbon re gan-an lojo ori.

Ninu alaye re, komisanna olopaa ipinle Eko, Fatai Owoseni, salaye pe dadi lomo yii n pe Akpan, momi lo si n pe iyawo re nitori awon mejeeji ni won to o dagba. Komisanna ni, ƒNigba tomo yii ti wa ni nnkan bii odun marun-un ni afurasi ti n se e basubasu, omo naa si ti pe odun meeedogun bayii. Lasiko to sa jade nile leyin ti afurasi ba a lasepo tan lawon olopaa kan ri i, ti won si mu un lo si tesan, leyin naa lowo te Akpan.

Ninu oro e, omobinrin ohun salaye pe, ƒNigba ti momi lo si Akwa-Ibom lose to koja ni dadi waa ba mi nigba ti mo n sun lale Sannde. Won fagbara bo aso mi, won si ba mi lasepo.

Toweeli ni won fi bo enu mi nitori se ni mo n sunkun, ti mo si n pariwo. Leyin iyen ni mo raaye sa jade, mo waa loo ba alabaagbe wa kan pe ko fun mi ni foonu re ki n fi pe momi.

Nigba to ni oun ko ni kaadi ipe ni mo sa lo sona ago olopaa kan, nigba ti mo si fee debe ni mo pade okunrin kan to ni oun maa ran mi lowo.

O mu mi lo si oteeli kan pe ka sun moju koun too mu mi lo sodo olopaa, sugbon nigba to fee ki mi mole ni mo pariwo ti eni to ni ibe fi wa. Bi mo se sare kuro nibe ni mo pade awon olopaa kan, awon lo si ni ki olokada kan gbe mi de ∆Lion Building«, leyin ti mo so nnkan to sele fun won.

E wo o, igba meji ni dadi ti fipa ba mi lasepo. Mo so fun momi nigba akoko to je odun to koja, won gba mi gbo, sugbon dadi ni nigba ti mo silekun sile lenikan wole to ki mi mole.≈ Sugbon oro ko dun lenu ole, Akpan, eni to je omo bibi ipinle Akwa-Ibom so pe oun ko mo gbogbo igba ti isele ohun waye rara nitori oun ti mu oti yo. O ni oun lo si isomoloruko omo ore oun kan lojo naa ni, nigba toun si de loun ki omo yii mole, bo tile je pe oun ko mo nnkan toun n se. O ni eekan pere niru e waye, asise si ni.

Gege bo tun se salaye, Bii omo lomo yii je si mi o, emi ni mo to o dagba, bawo ni ma a se waa mo-on-mo ba a lasepo. Eewo nla ni nnkan ti mo se, oti lo de fa a, se emi ti mo ti niyawo ni ma a waa deede ki omo yii mole?

Oro ti Akpan so ko ta leti awon to gbo o. Awon olopaa ni iwadii n lo lowo, laipe si ni afurasi naa yoo loo salaye ara re niwaju adajo.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 21:34:16 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Imeh Ha Sowo Olopaa L'Ekoo, Aburo Iyawo e Lo Se Kinni un Fun" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com