Gbagede Yoruba
 

 
Aliyu Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po n'Ilorin, Lo Ba Doyun
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga Lati Owo Akoroyin Olootu

Aliyu Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po n'Ilorin, Lo Ba Doyun

Kayeefi si ni isele to sele laduugbo Sakpefu, ni ona Lade, niluu Ilorin, si n je fawon eeyan nigba tokunrin olokada kan, Aliyu Tsado, to je omo ogun odun ki ero to gbe mole, to si fipa ba a lo po, eyi to pada waa ja soyun fomo naa.

Omodebinrin omo odun metala naa ti a foruko bo lasiiri ni akoroyin wa gbo pe adugbo kan naa loun ati Aliyu n gbe, asiko ti okunrin olokada naa pade re loju ona lo pe e pe dipo ti yoo maa fese rin, koun fokada gbe e dele. Leyin ti Aliyu gbe omo ohun lori okada re, ile ara re lo morile, nibi to ti fipa ba omo naa lasepo.

Iwadii awon olopaa fi han pe gbogbo bomo yii se pariwo pe kawon eeyan gba oun kale lowo okunrin naa ni ko reni kankan dide si i nitori paro ni gbogbo adugbo ohun da. Leyin ojo die la gbo pe baba omo naa sakiyesi pe o n re omo oun, idi ree to fi mu un lo sosibitu 'Cottage' to wa laduugbo Lade, niluu Ilorin, nibe ni won ti fidi e mule pe omodebinrin yii ti loyun.

Nigba ti won te e ninu daadaa lo daruko Aliyu, o si salaye boro ti je gan-an. Bee lo tun di mimo fun wa pe omokunrin olokada yii jewo fegbon re atawon agbaagba adugbo naa pe loooto loun fipa ba omodebinrin ohun lo po.

Lowolowo bayii, oyun n be ninu omobinrin omo odun metala yii, awon obi e si ti mu oro naa lo si tesan olopaa. Won ti taari ejo Aliyu lo siwaju Adajo S.B Olanipekun, nibi ti Sajenti Sanni to gbenuso fun ijoba ti fesun biba omode lasepo pelu ipa to tako abala kokanlelogbon iwe ofin eto awon omode tipinle Kwara, todun 2006, kan an.

Bo tile je pe Aliyu loun ko jebi esun naa, ti agbenuso olopaa si tako gbigba beeli re, Adajo S.B Olanipekun pase pe ki won si loo fi i pamo sogba ewon to wa l'Oke-Kura, niluu Ilorin.

O sun igbejo siwaju.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 19:46:49 PST Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Aliyu Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po n'Ilorin, Lo Ba Doyun" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com