Adebowale Atawon Egbe e Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po
Lati Owo Akoroyin Olootu
Adebowale Atawon Egbe e Fipa Ba Omo Odun Metala Lo Po
Afi ki ijoba ipinle Eko tete wa nnkan se soro ifipa-ba-ni-lo-po to n fi gbogbo igba waye ko too di pe o buru ju bo se wa yii lo loro to n tenu awon ero iworan kootu majisreeti Yaba jade lose to koja nigba ti won gbo esun ifipa-ba-ni-lo-po ti won fi kan awon omodekunrin meta kan ti ojo-ori won ko ju odun merinla si merindinlogun lo.
Ohun ti a gbo ni pe omobinrin omo odun metala kan ti a foruko bo lasiiri ni awon olujejo naa, iyen Elijah Adebowale, Suleiman Balogun ati Shefiu Adam pelu awon meta kan towo ko ti i te fipa ba lasepo lojo karun-un, osu kewaa, odun yii, nile akoku kan to wa laduugbo Olopade, ni Iju-Ishaga, l'Ekoo.
Agbenuso ijoba, Inspekito Rita Momah, so fun ile-ejo pe nigba tawon afurasi mefeefa ohun ri omo naa to n bo lati soosi ni won pe e pe ko waa ba awon loo ra oti eleridodo wa, bi iyen si ti de toun ti ohun ti won ran an ni won si okan ninu re, ti won si fi oti lile sinu e pe ko mu un.
Anfaani eyi la gbo pe awon omokunrin mefeefa yii lo ti won fi ribi wole si omodebinrin yii lara, ni kaluku won ba n yose lara e bii eni yose agbo omo.
Esun meji, iyen igbimo-po lati sise ibi ati ifipa-ba-ni-lo-po ti won fi kan awon olujejo meteeta yii, ti won so pe awon ko jebi re pelu alaye ni agbenuso ijoba so pe o lodi sabala irinwo o le mesan-an(409) ati metadinlogoje (137) tiwe ofin iwa odaran tilu Eko, todun 2011.
Ninu idajo re, Adajo F.A Adeeyo faaye beeli egberun lona oodunrun naira (N300,000) sile fun eni kookan won pelu oniduuro meji niye owo kan naa. O sun igbejo mi-in si ojo keje, osu kejila, odun yii.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Saturday, May 21 @ 21:31:57 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ