Gbagede Yoruba
 

 
'Omo Egbon Mi Loko Mi Fun Loyun, Mi O Fe e Mo'
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga Lati Owo Akoroyin Olootu

'Omo Egbon Mi Loko Mi Fun Loyun, Mi O Fe e Mo'

Adajo kootu ibile kan n'Ilesa ti tu igbeyawo ogbon odun to wa laarin Arabinrin Folake to je eni aadota odun atoko re, Kolade, toun je ogota odun ka lori esun tobinrin naa fi kan oko re pe o fun omo egbon oun kan to n je Kemi to n gbe lodo awon loyun.

Nigba to n soro niwaju adajo, Folake salaye pe oko oun je alagbere, sugbon o ti fiwa naa ba ara re je lodo awon ebi oun bayii pelu bo se fun Kemi to je omo odun metadinlogun loyun.

Oyun naa lo ni won gbiyanju lati se, sugbon to ko lati baje leyin tomo naa ti lo opolopo oogun ibile.

Pelu omije loju ni obinrin naa fi ro ile-ejo pe won gbodo tu igbeyawo ohun ka lai fakoko sofo nitori oun ko le maa ba aburo oun sorogun ninu ile Kolade, ati pe omo ti Kemi ba bi pelu awon omo oun yoo waa je omo baba kan naa.

Nigba ti Folake n dahun si ibeere adajo lo ni oyun naa wa losu meta bayii, ati pe oun ti yo owo oun ninu igbese lati ba oyun naa je lati ma seku ojiji pa Kemi nitori pe ko ti i to eni to n loyun lasiko toko oun fun un loyun.

Sugbon nigba ti Kolade n wi awijare re niwaju adajo lo salaye pe ise esu ni ohun to sele soun, bee lo je ohun ibanuje ti eti ko gbodo ba oun gbo.

Okunrin naa ro adajo lati ma se tu igbeyawo naa ka, o ni oun yoo wa ona abayo lati ri i pe oyun osu meta naa baje ko too dagbasoke si i. O tun be ile-ejo pe ki won sun igbejo siwaju si koun le raaye satunse lori oro naa.

Si idahun lori ibeere miiran ti adajo takoto re si Folake, obinrin naa fesi pe oro naa ti ba nnkan je debii pe ko si atunse mo nitori awon ebi, ore atawon mi-in ti gbo si i, o si ti daja sile laarin oun pelu Iya Kemi to je egbon oun. O ni nnkan kan soso to le pon oun le ni kileejo tu igbeyawo naa ka koun le raaye ara oun.

Leyin atotonu awon mejeeji ni adajo tu igbeyawo naa ka pelu ase pe kawon omo meta to wa ninu igbeyawo naa, iyen Dupe, Ife ati Sola maa gbe lodo iya won.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 04:54:30 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"'Omo Egbon Mi Loko Mi Fun Loyun, Mi O Fe e Mo'" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com