Abel Se 'Kinni' Fomo Odun Mesan-an L'Ondo, Ladajo Ba Ni Ko Loo Fe
Lati Owo Akoroyin Olootu
Abel Se 'Kinni' Fomo Odun Mesan-an L'Ondo, Ladajo Ba Ni Ko Loo Fewon Odun Marun-un Jura
O daju pe bi okunrin kan toruko re n je Onoja Abel ba n fowo lasan fa, yoo ti maa gbadun ara re ninu ogba ewon Olokuta to fikale siluu Akure, nibi tadajo ile-ejo majisreeti kan niluu naa pase pe ko ti loo maa se faaji fodun marun-un lori bo se jebi esun fifipa ba omodebinrin eni odun mesan-an kan lo po.
Isele naa waye losu to koja, ni nnkan bii aago mefa irole ninu ogba kan ti won ti n ta omi inu ora lagbegbe High School, l'Akure, nibi ti Abel ti fogbon tan omo naa toruko re n je Precious Nwakocha, to si fipa ba a lo po.
Esun meji ni won ka si Abel lese nile-ejo, akoko ni pe o fipa ba omodebinrin yii lo po, eyi ti agbefoba, ASP Isah Atanegbe, so pe o lodi sabala ofin okoolelugba-o-din-meji tiwe ofin iwa odaran ipinle Ondo, todun 2006. Esun keji je fifi abuku kan omo naa pelu bo se fowo te e loyan lai gba ase lowo re, eyi to tako abala ofin otalelooodunrun (360) tiwe ofin ipinle Ondo, todun 2006.
Loju-ese ti won ka esun yii tan ni okunrin to pe ara re lomo odun metalelogun so niwaju adajo pe loooto loun jebi gbogbo esun naa. O ni ko siro ninu ohun ti won ro lejo, loooto loun ba omo naa lo po leekan pere ninu osu kesan-an, nigba toun se kinni ohun fun un leemeji ninu osu kewaa, eyi to mu ko je igba meta pelu ipa.
Abel so pe eyin ogba ile ohun loun tan Precious lo, nibi toun ti seleri fun un pe oun setan lati fe e bo ba le gba koun ba a lasepo.
Niwon igba ti Abel si ti gba pe oun jebi esun ti won fi kan an lai wule fakoko ile-ejo sofo, Adajo Victoria Bob-Manuel ni ko loo fewon odun marun-un gbara lori esun ti won fi kan an yii.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 04:33:48 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
"Abel Se 'Kinni' Fomo Odun Mesan-an L'Ondo, Ladajo Ba Ni Ko Loo Fe" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ