Okunrin Mi-in N Se Kinni un Fun Iyawo Mi Ninu Ile Wa, Mi O Fe e Mo — Babatunde
Lati Owo Akoroyin Olootu
Okunrin Mi-in N Se Kinni un Fun Iyawo Mi Ninu Ile Wa, Mi O Fe e Mo — Babatunde
Kootu ibile kan n'Ilesa ni Ogbeni Babatunde, eni ogoji odun, gbe iyawo re, Omolola, lo lori esun agbere to fi kan an, o si ro ile-ejo naa pe ko tu won ka lai fakoko sofo.
Nigba ti Babatunde n soro niwaju adajo lo salaye pe ni nnkan bii ose meji seyin loun ba iyawo oun, Omolola, pelu okunrin kan to n je Adetayo lori beedi oun ti won n ba ara won sere ife.
Babatunde ni ise olokada loun n se, sugbon lasiko tomo awon, Tope, jade nileewe loun gbe e lo sile, nibi toun ti ba iyawo oun ti won n ko ibasun fun un lowo. O ni nitori toun ko fe ki Adetayo ohun salabaapade iku ojiji latowo oun ni oun fi loo fejo re sun lagoo olopaa to wa n'Ijamo, niluu Ilesa.
Okunrin naa ni oun fe Omolola lodo awon ebi re ni nnkan bii ogun odun seyin, ti omo meji, Tope ati Tolu si wa ninu igbeyawo naa, ati pe ko sohun tiyawo oun beere lowo oun ti oun ko se fun, sugbon o je ohun iyalenu foun bi obinrin naa se gun le agbere sise, eyi to le fa iku ojiji foun.
Babatunde soro siwaju so pe tile-ejo ba ko ti ko tu igbeyawo naa ka, eni kan ninu awon yoo jepe orun laipe, nitori pe ibikibi toun ba ti pade Omolola nigboro Ilesa ni yoo maa koju iya jije latowo oun.
Bii igba meji otooto tile-ejo ti fi iwe pe Omolola lati wa sile-ejo waa so tenu e ni ko yoju, sugbon to fiwe ranse pe oun faramo kile-ejo tu igbeyawo naa ka.
Nigba ti adajo n gbe ipinnu re kale, o kilo fun Babatunde lati gba alaafia laaye, bee ni ko si gbodo ba Omolola ja nibikibi to ba ti salabaapade re nitori yoo te ofin loju mole, yoo si ri ijiya labe ofin. Bayii lo tu igbeyawo naa ka, to si pase pe kawon omo mejeeji to wa ninu igbeyawo naa wa lodo baba won.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 04:15:14 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
"Okunrin Mi-in N Se Kinni un Fun Iyawo Mi Ninu Ile Wa, Mi O Fe e Mo — Babatunde" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ