Gbagede Yoruba
 

 
Animasahun Niyawo Ti Mo Fe, Mi O Se Mo Ayokunle
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga Lati Owo Oluseye Iyiade, Akure

Animasahun Niyawo Ti Mo Fe, Mi O Se Mo — Ayokunle

Afi k'Olorun yaa tete da si wahala to ti ridii jokoo ninu idile kan l'Akure, bi bee ko, igbeyawo odun mejidinlogun ohun ti wa ni bebe ati fori sanpon pelu bi baale ile naa se wo iyawo re wa si kootu koko-koko to wa niluu naa pe ki adajo fopin si ibasepo olodun gbooro to wa laarin oun pelu iyawo re kia.

Okunrin eni ogoji odun naa, Bamidele Ayokunle lo wo iyawo e, Folasade Ayokunle, wa si kootu to n gbejo loko-laya to wa l'Oke-Eda, niluu Akure, to si fesun agbere kan an. O ni iyaale ile naa ko mo enu i yipada bi okunrin ba kenu si i, bee ni ko si mo on ko fun gbogbo okunrin to ba ti gbe e sunmo on.

Bamidele to n sise kapenta so ni kootu pe o pe toun ti n farada kinni ohun fun iyawo oun, sugbon nibi toro de duro bayii, se lo da bii eni pe kinni naa ti di baraku fun un, bee loun ko le mu un mora mo lati maa ba a gbe po bii toko-taya.

O fi kun un pe iwa isekuse to ti wo Fokasade lewu ki i sohun to pamo rara fawon tawon jo n gbele. O ni lara won gan-an lo koko pe akiyesi oun siwa agbere tiyawo oun n hu kiri.

Koda, o ni iyawo oun ti so o kan oun loju ri pe ki oun joo, gba oun laaye lati mu ise asewo loju paali, kawon le maa rowo na lai si wahala ninu idile awon.

Esun keji tokunrin yii fi kan iyawo re ni pe ija lo maa n gbe ko oun loju nigbakigba ti ko ba ti sowo lowo oun. O ni bi Folasade ba bere ija re bayii, nise ni yoo maa ba dukia toun fowo iyebiye ra je.

O lo to igba marun-un otooto tawon ti kora awon lo sile-ejo lori awon iwa palapala to kun owo re yii, sugbon kaka ki obinrin yii duro lori ileri to se pe oun ko tun je ba oun fa wahala kankan mo, nise ni yoo tun gun le iwa ohun.

Nigba ti Folasade n rojo tire, o se; si gbogbo esun toko e fi kan an, bee lo ro igbimo onidaajo pe ki won jowo, ba awon yanju oro naa nitori oun ko setan lati keru kuro nile oko oun.

O ni ko si nnkan meji to maa n fa wahala laarin oun ati baale ile naa ju pe okunrin naa ki i sojuse re bii oko. O ni ki i toju oun atawon omo, opelope awon araadugbo kan ti won n fun oun lounje ni ko je ki ebi ti pa oun atawon omo ku.

O ni okan lara awon eleyinju aanu (ti ko daruko e) to n gbe laduugbo won lo ba oun sanwo ileewe abigbeyin awon.

Nigba ti alaga igbimo onidaajo eleni meta ohun n gbe ipinnu e kale, Abileko Olayinka Falodun fidi e mule pe oro awon omo to wa laarin toko-taya yii se pataki pupo sijoba, awon lo si maa n saaba fara gba wahala to ba suyo ninu igbeyawo ti opin ba de ba.

O waa pa a lase fun toko-tiyawo naa lati mu elerii meji meji wa si kootu lojo kokanla, osu to n bo, ti won sun igbejo mi-in si.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 03:06:17 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Animasahun Niyawo Ti Mo Fe, Mi O Se Mo Ayokunle" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com