Larry Fipa Ba Omo Odun Mejo Lo Po N'Iju, Ni Won Ba Wo o Dele-ejo
Lati Owo Olowoake Latifat
Larry Fipa Ba Omo Odun Mejo Lo Po N'Iju, Ni Won Ba Wo o Dele-ejo
Okunrin eni odun metadinlogbon kan, Larry Atipko, ni won safihan re bii afurasi odaran nile-ejo majisreeti to fikale si Yaba lose to koja lori esun pe o fipa ba omodebinrin odun mejo kan to je omo araale re lo po pelu ipa.
Gege bi ohun ta a ri gbo, ki i se igba akoko ree tokunrin ti won pe loree timotimo ebi omode yii yoo fipa mu omo naa mole ninu yara re ba a ni nnkan po. Sugbon eyi to se keyin lojo ketadinlogun, osu kesan-an, odun yii, lowo ti te olujejo naa to n gbe lojule Kin-in-ni, laduugbo Tunji Adesayo, Fagba, Iju.
Agbenuso ijoba, Rita Momah, so pe anfaani pe ile kan naa ni okunrin yii pelu awon obi omo naa n gbe lo lo lati wo omo ohun wonu yara e, to si se bee ba iyen lo po lai tie wo pe o kere pupo soun.
Esun kan soso naa ti ijiya e pe fun ewon gbere ni agbenuso yii so pe o tako abala ketadinlogoje(137) iwe ofin iwa odaran tipinle Eko, todun 2011.
Bo tile je pe Larry so pe oun ko jebi esun naa, adajo ile-ejo yii, Arabinrin F.A. Adeeyo, pase pe ki won fi eda iwe ipejo ohun sowo si adari to n ri seto igbejo nipinle naa fun imoran. Bee lo faaye owo beeli tiye e to egberun lona igba naira ati aadota naira sile fun un pelu oniduuro meji ti won niru owo bee nipamo.
O waa sun igbejo siwaju di ojo karundinlogbon, osu kokanla, odun yii.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 01:49:11 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
"Larry Fipa Ba Omo Odun Mejo Lo Po N'Iju, Ni Won Ba Wo o Dele-ejo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ