Gbagede Yoruba
 

 
Awon Omo Keekeeke Loko Mi n Gbe Kiri, Mi O Se Mo Folake
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga Lati Owo Akoroyin Olootu

Awon Omo Keekeeke Loko Mi n Gbe Kiri, Mi O Se Mo — Folake

Arabinrin Folake, eni ogota odun ti gbe oko re, Ogbeni Odewole, lo sile-ejo ibile kan n'Ilesa lori esun agbere sise pelu bo se maa n ba awon odomobinrin tojo ori won ko ju ogun odun lo sagbere, ti yoo si maa kowo fun won.

Gege bi Folake to je osise-feyinti ileese ologun se so, o ni lati igba ewe Odewole, lo ti n se agbere, sugbon kaka kewe agbon re de, lile lo n le si i nitori bi ko se fiwa naa sile titi di asiko yii to ti darugbo.

Foluke tesiwaju pe oun ti lojo lori lati gbe iru igbese toun gbe yii, ifokanbale ati alaafia loun nilo titi ti olojo yoo fi de.

Obinrin naa ni bi Odewole se n da luru po mo sapa, ti dudu n wole, ti funfun n jade le sakoba foun, paapaa julo bi arun kogboogun se di toro-kobo nigboro. O waa ro ile-ejo naa lati tu igbeyawo opolopo odun to wa laarin oun atoko re ka lati fun un ni ayo okan lodo awon omo re.

Sugbon nigba ti Odewole n soro niwaju adajo, o ni Folake je onitara eeyan ti ki i fee ri obinrin mi-in pelu oun, eyi to ti n hu latigba tawon ti segbeyawo. Bee lo koro oju si bi obinrin naa se gbe e wa sile-ejo lai foro naa to awon omo ti won wa ninu igbeyawo naa leti lati fowo si i.

Odewole waa ro ile-ejo naa lati ma tu igbeyawo ohun ka nitori pe oun ko koyawo oun, ati pe eso omo merin tigbeyawo ohun so (Dupe, Bunmi, Korede ati Pelumi) ko fowo si ikosile awon.

Ninu ipinnu adajo ile-ejo naa lo ti gba toko-taya naa niyanju lati pada lo sile lati tun ero won pa, ki won si wa so ibi ti won fori oro naa ti si fun ile-ejo.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Friday, April 29 @ 00:34:36 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Awon Omo Keekeeke Loko Mi n Gbe Kiri, Mi O Se Mo Folake" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com