Gbagede Yoruba
 

 
Owo Ajo Sifu Difensi Te Wolii To Fipa Ba Omo Odun Meeedogun Lo Po L'Ondo
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Owo Ajo Sifu Difensi Te Wolii To Fipa Ba Omo Odun Meeedogun Lo Po L'Ondo

Lojo Abameta, Satide, ose to koja lohun-un, lowo ajo Sifu Difensi ipinle Ondo te okunrin wolii kan nibi to ti n sere egele pelu omodebinrin kan, Tosin, okan ninu awon omo ijo re to je eni odun meeedogun.

Gege bi ohun t'Iwe Irohin Yoruba fidi e mule nipa isele naa, wolii ohun ti won pe oruko re ni Jacob Olasupo Ojomo to je oludasile ijo Kerubu ati Serafu, to wa ni Apata Iloro, lagbegbe Oke-Ijebu, niluu Akure, ni won fesun kan pe bo se n ba omodebinrin naa lo po, bee lo n gba nnkan mo nnkan fun iya omo yii.A tun ri i gbo pe o ti pe tawon eeyan kan laduugbo naa ti won mo nipa itu ti Wolii Jacob maa n fi awon omobinrin inu ijo re pa, sugbon ti won ko ti i gba a lorun owo mu ni ko se je ki won kegbajare re sita.

Wolii ohun la gbo pe o je eni akoko ti yoo fipa ba Tosin lo po ninu osu kejila, odun to koja, iyen lojo to fipa ja ododo omo olomo. Isele naa lo mu iya omo naa, Abileko Olayemi Aluko, fi binu kuro ninu ijo okunrin wolii yii.

Leyin-o-reyin lawon a-gboro-dun kan ti iya ohun foro lo fun un lamoran pe afi ko tun pada si soosi Wolii Jacob bo ba fe ki asiri ohun to se fomo re tu sita, eyi to mu ki iyaale ile naa atomo re pada si soosi ohun lati maa loo josin nibe, sugbon ti oludasile naa ko mo pe won fee waa sode oun.

Lojo Abameta, Satide, tisele taa n soro re yii waye ti Eni-owo Jacob ro pe Iya Tosin ti lo si irin-ajo lo se mu kokoro yara e fun omo yii ni nnkan bii aago marun-un irole ojo naa pe ko loo duro de oun nile oun ti ko fi bee jinna pupo si soosi yii.

Ni kete ti iranse Olorun naa so fomo naa pe ko loo duro de oun nile odo e lomo ti ranse sawon a-gboro-dun to n so o, bee lawon yen naa ko si da oro naa se pelu bi won se ranse sajo Sifu Difensi pe ki won tete maa bo waa wo ohun to fee sele.

Awon osise ajo naa atawon eeyan yii ni won sapamo sitosi ile ti Wolii Jacob n gbe, ti won n reti ohun to fee danwo to fi ni ki Tosin loo duro de e nile.

Se loro ohun da bii igba pe wolii yii ti fura pe won le maa so oun pelu bi ko seni to mogba to wole loo ba omo naa ninu ile.

Nigba ti aago meje ale n loo lu, tawon ti won n so o ko reni to jo pasito ohun ko wole, ti won ko si romo ko jade lo mu ki okan ninu won lo sibi ferese yara okunrin yii lati feti lele gbo ohun to le maa sele ninu yara nibe.

Eni to loo teti sibi windo gbo wuruwuru pe awon eeyan wa ninu yara naa, eyi lo si mu un sare loo pe awon to ku ti won sapamo sinu oko. Awon eeyan ohun pelu iranlowo awon osise ajo Sifu Difensi ni won si fipa silekun palo wolii naa pe boya won a je ba a lori omo odun meeedogun yii ki won le wo o jade nihooho, sugbon ki won too ro wole tan ni won ni okunrin naa ti n wo sokoto re, to si je pe pata ni Tosin n wo lowo.

Tosin lo sese waa fidi e mule fawon agbofinro ohun pe Wolii Jacob ti se ohun to fee se tan ki won too wole. O ni idi toun ko se pariwo bi won se so foun tele ni pe okunrin naa hale mo oun pe boun ba fi le pariwo, pilo loun maa fi fun oun lorun pa ti ko si seni ti yoo beere oku oun lowo re.

Omodebinrin yii tun fidi e mule pe nigbakuugba ti pasito naa ba ti ba oun sun, o ni ki i da nnkan omokunrin re soun labe, ita lo maa n da a si ko too di pe yoo sese waa fi aso penpe nu oju ara oun ati nnkan omokunrin re.

Wolii ohun se kanle pe oun ko ti i ba omodebinrin yii se ohun to jo bee, pe iro ni Tosin n pa mo oun, eyi lo si mu kawon to wa nibe maa beere lowo re ise to n fi foomu to gbe sile ni palo re se, ati idi to fi n laagun yobo lale ojo naa.

Loju-ese ni won ti gbe Tosin lo sileewosan ijoba, nibi ti dokita ti fidi e mule pe loooto ni won ba a lasepo lojo naa bo tile je pe won ko ri nnkan omokunrin loju ara re.

Lale ojo Abameta, Satide, ohun, lajo Sifu Difensi fi panpe ofin gbe Wolii Jacob, ko too di pe won gbe e lo sile-ejo majistreeti kan niluu Akure, nibi tadajo ti ni ki won gba beeli re pelu egberun lona eedegbeta naira.

Leyin ti won gba beeli okunrin yii tan ni won lawon eeyan re bere si i fi iya omodebinrin ohun se yeye nileejo pelu bi won se ni won ti n be e tele pe ko ba won pa oro ohun mole, sugbon ti ko gba si won lenu.

Osise ajo Sifu Difensi kan taa foruko bo lasiiri so fun wa pe loooto ni Iya Tosin ti wa ba awon pe kawon jawo kuro lori oro naa, sugbon tawon so fun un pe ejo ko si lowo awon mo, o ti di tijoba.

Ninu oro Tosin funra re lo ti salaye pe aso ni Wolii Jacob be oun pe koun waa ba a fo nile ninu osu kejila, odun to koja, ko too di pe o fipa ba oun lo po, to si so oun dobinrin lojo naa.

Ni ti eyi to sele gbeyin yii, Tosin so pe ogorun-un naira ni eni-owo naa fun oun lojo naa leyin to setan, bee lawon eeyan to ro wole si ba owo naa lowo re nigba ti won wole.

Abileko Olayemi to je iya omodebinrin yii naa fidi e mule pe loooto ni ife ikoko wa laarin oun ati Wolii Jacob. O ni leyin toun fibinu loo ba a leyin tomo oun so foun pe o n ba oun lajosepo lodun to koja, o ni ko si epe ti wolii yii ko gbe ara re se tan lati se; si esun naa ko too waa di pe asiri re tu lose to koja.

O se ni laaanu pe a ko ba okunrin wolii yii nile nigba taa sabewo sibe l'Ojobo, Tosde, ose to koja, lati fidi oro ohun mule, sugbon obinrin kan to ba wa soro laduugbo tokunrin naa n gbe so pe won kan fee fi isele ojo naa ba okunrin yii loruko je ni, nitori to n mura lati dupo pataki kan laarin awon asaaju ijo Kerubu to wa l'Akure. O ni idi ni pe awon alatako re mo daju pe awon eeyan nifee re daadaa.

Obinrin naa fi kun oro re pe bi ojo ori Tosin taa n soro re yii se kere to, gbogbo eeyan lo mo pe isekuse re ko legbe laduugbo yii.

Alukoro ajo Sifu Difensi nipinle Ondo, Ogbeni Kayode Balogun, naa fidi isele naa mule, o loro naa ti deleejo, ati pe idajo kootu lo ku ti won n reti lori oro ohun.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 16:30:00 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe"Owo Ajo Sifu Difensi Te Wolii To Fipa Ba Omo Odun Meeedogun Lo Po L'Ondo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com