Gbagede Yoruba
 

 
Olode Ile-eko Alakoobere Fipa Ba Omoleewe Lo Po N'Ilorin
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
Lati Owo Olayinka Adedayo

Olode Ile-eko Alakoobere Fipa Ba Omoleewe Lo Po N'Ilorin

Ogbeni olode kan, Appolos Isaiah, ti fipa ba odomodebinrin omo odun mesan-an kan lo po ni ile eko to ti n sise ode laduugbo Taiwo-Isale, niluu Ilorin, bayii.

Gege bi akoroyin wa se gbo, ojo kejidinlogun, osu to koja, nisele naa waye. Isaiah ni iwadii akoroyin wa fihan pe o n sise pelu ileese eleto aabo Ogboye-s Security Company ti won si fi i si ile eko alakoobere Methodist Nursery and Primary School' to wa ni adugbo TaiwoIsale.

Akoroyin wa ri i gbo pe nise ni Isaiah fogbon pe omodebinrin naa ti a foruko bo lasiiri yii, to si tan an wo ile ode to wa ninu ogba ileewe naa, nibe lo si ti fipa ba a lo po.Enikan to ba akoroyin wa soro sugbon to ko lati daruko re salaye pe nise ni Isaiah fipa ba omo naa lo po, leyin eyi lo tun faso funfun nu oju ara re. Won ni Isaiah ko ipaya ba omo yii pe ko gbodo so nnkan to sele fun enikeni, sugbon okete boru mo on lowo nigba tomo naa bere si i lonu mole nile, eyi lo si fa a ti awon obi e fi te e ninu daadaa ko too di pe o pada tu asiri nnkan to sele.

Lesekese lawon obi e gba tesan olopaa lo, tawon agbofinro naa ko si fakoko sofo ti won fi nawo gan Isaiah. Gbogbo akitiyan akoroyin wa lati ri awon obi ati olori ile eko alakoobere naa ba soro lo ja si pabo pelu bi igun mejeeji se ni awon ko ni ohun tawon fee so lori isele naa.

Nigba ti n fidi isele yii mule fun akoroyin wa, alukoro ileese olopaa ipinle Kwara, ASP Ajayi Okasanmi, so pe loooto nisele naa sele, ati pe iwadii awon si n tesiwaju lori isele naa.

Gege bo se so, "Nise ni okunrin kan toruko re n je Appolos Isaiah, fipa ba omodebinrin omo odun mesan-an kan lo po ni nnkan bii aago mejila aabo osan nigba tawon akekoo si wa nileewe ni Methodist Nursery and Primary School', Taiwo-Isale, niluu Ilorin."

"Nise ni okunrin olode naa fi aso ankasiifu funfun nu oju ara omodebinrin yii, to si ki i nilo pe ko gbodo so nnkan to sele laarin awon fun enikeni."

Sa, Okasanmi fidi e mule fun akoroyin wa pe awon ti taari ejo naa si kootu, nibi ti olujejo yoo ti loo maa so tenu re fun adajo.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 15:50:52 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Olode Ile-eko Alakoobere Fipa Ba Omoleewe Lo Po N'Ilorin" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com