Gbagede Yoruba
 

 
Aye Yii Ti Baje O! Omo Odun Meta Ni Hassan Fipa Ba Lo Po N'Ilorin
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
Lati Owo Taofeek Surdiq

Aye Yii Ti Baje O! Omo Odun Meta Ni Hassan Fipa Ba Lo Po N'Ilorin

Ileese olopaa ipinle Kwara ti taari okunrin olokada kan, Hassan Bawa, eni odun mejidinlogoji lo si kootu majisreeti to wa niluu Ilorin niwaju Adajo A.M Ibrahim latari pe o fipa ba omo odun meta kan lo po.

Gege bi esun ti agbefoba to n rojo tako o nile-ejo fi kan Hassan, ni nnkan bii aago mejila osan ojo kokandinlogun, osu kesan-an, odun yii, ni Arabinrin Abibat Ojo to n gbe ni abule Aboto Oja, nijoba ibile Asa, nipinle Kwara, mu esun lo si tesan olopaa ni Afon pe lojo kejidinlogun, osu to koja yii ni oun de lati ibi ise ni nnkan bii aago meje ojo naa, toun si ri i pe oun ko ri omo oun obinrin omo odun meta ta a foruko bo lasiiri.Abibat salaye siwaju fawon olopaa pe nibi toun ti n wa omo oun yii kiri ni arakunrin kan, Hassan Bawa, tawon jo je alajogbe ti jade ninu yara re pelu omo oun yii lowo, nigba toun si ye ara omo oun wo daadaa loun ri i pe ato okunrin (semen) wa loju ara re. Akiyesi yii loun se toun fi figbe ta, tawon si mu esun lo si ileese otelemuye n'Ilorin. Iwadii ileese otelemuye lo fidi re mule pe se ni Bawa fi agba re omode yii je, to si fipa ba a lo po.

Nigba ti ileese olopaa po Hassan nifun po lo jewo pe loooto oun jebi esun naa, won ko si besu-begba ti won fi taari re lo siwaju Adajo A.M Ibrahim. Agbenuso ijoba rojo tako Hassan ni kootu, o si tako gbigba beeli re pelu alaye pe ese to se buru jai ni.

Ni bayii, won ti taari Hassan lo si ogba ewon to wa niluu Ilorin, nibi to ti n gba ategun lowolowo.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Wednesday, October 14 @ 15:31:58 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Aye Yii Ti Baje O! Omo Odun Meta Ni Hassan Fipa Ba Lo Po N'Ilorin" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com