Gbagede Yoruba
 

 
Asiri pasito to n ba awon iyawo oniyawo sun n'Ibadan tu
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga Lati Owo Olawale Ajao, Ibadan

Iroyin Yoruba

Lakooko ti aawe lenti awon omoleyin Jesu n lo lowo, ti opopolo Kristeni n toro idariji ese, ti won si n tera mo ise rere lati ri ijoba Olorun wo, iyawo oniyawo lokunrin iranse Olorun kan, Pasito Sunday Moradeyo, n ba sun kiri, nise lo n loo ka won mo oode oko won, to si n ko ibasun fun won karakara.

Oke aimoye iyawo oniyawo ni Pasito Sunday ti ko ni aya loode yii ti se bee ba lasepo, oun paapaa so pe oun ko le ranti iye won lori, nitori o kere tan, oun ko le ma ba obinrin kan lo po lojumo, bee, odun karun-un ree toun ti bere ise buruku ohun.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe lati ojule de ojule, soobu kan si ekeji lokunrin to pera e leni ogbon odun yii n gbe kinni naa loo ka awon obinrin olobinrin mo. Ko si ohun meji to maa n ba won so koja oro nipa ise idande ati igbala atorunwa, ka si too wi, ka too fo, o ti da adura nla bole bii owara ojo.

Nise ni yoo di won lowo mu, nibi tawon onitohun ba si ti n se amin-amin kikankikan bii obo to kagbako lowo ekun lokunrin naa yoo ti wole si won lara, nitori bi eto adura ohun ba ti pari ni yoo mu ororo igo kan jade ninu apo re, bi eni naa ba si ti gba ko fi abami ororo naa ra oun nitan, wolii eke naa yoo ti ba tohun ni ajosepo tan ki oluware too mo nnkan to n sele.

Lojo Abameta, (Satide), ti i se ojo ketadinlogbon, osu keji, odun yii, lowo palaba e segi, iyen nigba ti araadugbo Idi-Iroko, lona Amuloko, n«Ibadan, kan, Ogbeni Abiodun Adegoke, ka a mo yara enikan, nibi to ti n sadura fun iya oniyaa laduugbo naa pelu erongba lati ba a lasepo, o si ti n mura lati ka aso iya naa soke lati fi abami ororo ra a nitan.

Saaju, iyen lojo Eti, Fraide, ojo kejidinlogbon, osu naa, ni Sunday ti koko lo sile iya ta a foruko bo lasiiri naa, to si so fun un pe oun yoo seto akanse adura olojo meje kan fun un.

Sugbon bo se di pe pasito naa di iya yii lowo mu ni ara ti bere si i fu obinrin naa, eyi lo mu un loo fi oro ohun to Ogbeni Adegoke leti, ti won si ti reke sile ko too de.

Bi Pasito Sunday se de ni nnkan bii aago mokanla aaro ojo keji ni iya naa to ti fee to eni aadota odun ti loo so fun okunrin alabaagbe re ohun, tiyen si loo ka a mo ibi to ti n sadura iro fobinrin olobinrin ninu ile oko e, nitori ti oko iya naa ko si nile.

Nigba ti Adegoke, eni to je igbakeji alaga egbe awon onile adugbo Moga hale mo on daadaa lo jewo pe ki won ma pa oun, oun setan lati jewo. Oni ki i se nitori Olorun loun se n se akanse adura naa, bi ko se koun le rogbon wole si i lara, koun si ba a lasepo, ati pe pasito kan to tun ju oun lo ninu ise esu naa lo ran oun ni awon ise buruku yii.

Gege bi Ogbeni Adegoke se so, ƒBi Pasito Sunday se de lojo yen lobinrin yen ti sare waa so fun mi. Mo waa fi won lara bale fun bii iseju marun-un ki n too lo. Mo ba won nibi ti won ti n gbadura ni palo awon iya yen. Mo ni, ∆Pasito, e ku ise Oluwa o, bawo lo se je o@« Obere si i puro, mo ba fee bo aso lorun e, mo ni wo o, ihooho lo maa rin jade nibi lonii to o ba jewo ohun to o waa se nibi. Oni ki n ma ja oun sihooho, oun yoo jewo. Oba ni toun ba ti fi ororo yen si won nitan bee yen, won ko ni i mo ohun ti won n se mo titi toun yoo fi ba won sun. Oni nnkan kan wa toun maa n to la koun too jade loo se awon iru nnkan bee. Bi mo se mu un ti mo fa a le egbe awon lanloodu lowo niyen, mo si fi han gbogbo araadugbo ki won le maa sora pelu e nibikibi ti won ba ti ri i.

ƒAba kaadi idanimo to n lo ninu apo re to je pe CAC Oke Alaafia ni Orita-Merin. Oni ayederu ni kaadi yen, oga oun lo fun oun. Nitori pe a ko fe kiru eyi maa waye mo la se mu un lo sinu ipade egbe awon alaga egbe lanloodu gbogbo adugbo Moga lapapo.≈ Iya ti Sunday fee ba ni nnkan po ko too di pe asiri e tu so fakoroyin wa pe pasito gidi loun pe e nigba toun koko ri i toun fi gba pe ko saduura foun laimo pe eni esu pombele ni i se.

Iya to ti fee to eni aadota odun yii salaye pe, ƒNibi ti won ti n ta oogun niwaju soobu mi ni mo ti koko ri i.

Jenereto eni yen lo n yonu ti pasito yii fi bere si i saduura si i pe ko sise. Nigba ti mo ti ri i bee yen, pasito gidi lemi pe e, emi naa si n saduura kan lowo nigba yen. Bo se kuro lodo eni yen lo koja legbee mi, o ba tun pada, lo ba ni Olorun ran oun si mi. Oni enikan wa to je pe emi pelu e ti ja tipe, pe eni yen ti mu foto mi lo sile oloogun.

ƒEmi ati enikan ja nigba kan loooto, mo waa ro pe iyen lo n so ni. Oni ki n je ka lo sile loo gbadura, mo ni rara, ibi soobu wa ta a duro si yii naa ti daa. Nigba to n gbadura lowo lo ni ki n je ka di ara wa lowo mu, mo ni emi ko feran iru adura bee. Mo ni bawo ni mo se maa di i lowo mu nigba ti mi o mo on ri. Osaa gba adura to ni i gba fun mi, o ni oun tun maa wa lojo keji nitori ojo meje loun yoo fi gbadura naa, mo si ni ko si wahala. Ose adura yen tan, o ni ki n fun oun ni apo kan aabo naira, emi wo o pe eeyan kuku n rin o n so owo nu, mo ba fun un.

ƒBo se de lojo keji ni omo mi waa so fun mi ni soobu pe enikan n beere mi, won si so pe ki n tete maa bo nile. Mo ni ko so fun eni yen pe mi o si nile, sugbon o ni eni yen n jokoo de mi nile. Emi ti soro e fun baba ti won n gbe eyin ile wa tele.

ƒNibi to ti n gbadura lowo lo ti so pe oun maa si itan mi soke, oun maa fi ororo owo oun si i. Mo ni iru radarada wo niyen. Nibe ni baba ti de. Mi o ri iru re ri latojo ti mo ti n ba igbesi-aye mi bo. Pasito gidi ni mo pe e ki n too gba fun un. Baba fee ja a sihooho gan-an lojo yen ni. Oko mi ki i gbele, Eko lo maa n wa.≈ Gege b«Iwe Iroyin Yoruba se gbo, ni nnkan bii odun meta seyin ni won ka Pasito Sunday mo ibi to ti n ko ibasun fun obinrin kan laduugbo ile to n gbe pelu awon obi e ni Orita Merin-Tioya, n«Ibadan, tawon ebi obinrin toro naa kan si fa a le awon olopaa lowo ko too di pe won fi ese ile to oro naa.

Awon obi Sunday mejeeji, Ogbeni ati Abileko Ajeigbe paapaa fidi oro yii mule fakoroyin wa, won ni lati nnkan bii odun meta seyin tomokunrin yii ti ba omo olomo sun lawon ti bere si i fi oro e sinu aawe ati adura, sugbon to se pe kaka ki ewe agbon re de, nise lo n le koko si i.

Nigba to n ba akoroyin wa soro, Pasito Sunday so pe oun ko le ranti iye obinrin toun ti ba lasepo, sugbon oun ranti pe o to eemarun-un toun ti ba iyawo ile kan to n je Tawa sun, bee obinrin naa ti bimo meta. Bakan naa loun ti mu obinrin kan to n je Sade bale leyin tiyen ti bimo meji, ati pe ninu ile oko won naa loun ti n ki won mole nitori awon toko won ko ba si nitosi tabi ti won ti lo sibi ise loun maa n se idande fun won.

Okunrin eni ogbon odun yii so pe baba kan to n je Pasito Kolawole Idowu Ajeigbe ni oga oun nidii ise naa, ati pe baba naa loun maa n jabo gbogbo rederede toun n se pata fun.

Iwe Iroyin Yoruba gbo pe iwe mewaa pere ni Sunday ka. Awon obi e ran an nileewe lati loo kekoo nipa ise olukoni nileewe olukoni ∆Emmanuel Alayande College of Education«, to wa niluu Oyo, sugbon nise lokunrin naa kan n gbowo lowo won nile, to si n na an ninakunaa lai se pe won gba a wole sileewe naa. Foto kan to ya pelu aso ti won fi n sayeye fawon akekoo ti won ba sese gba wole sileewe naa lo loo fi han awon obi e nile, tawon yen si ro pe o ti di ojulowo akekoo koleeji ohun ni tooto.

Sa, gbogbo awon okunrin adugbo Idi-Iroko ati gbogbo agbegbe Moga lapapo ni won ti kilo fawon iyawo won lati maa rin tifura-tifura, ki won ma baa bo sowo wolii eke to n pera e ni Pasito Sunday yii. Bee lo se pe toju-tiye lawon obinrin adugbo yii fi n riran lati ri i pe won ko faaye gba okunrin to n ja awon iyawo oniyawo lole ara naa ni sakaani won.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 18 @ 07:17:29 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Asiri pasito to n ba awon iyawo oniyawo sun n'Ibadan tu" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com