Mudasiru pa iyawo re ti pelu oyun osu meji, lo ba sa lo siluu oyinbo
Lati Owo Akoroyin Olootu
Mudasiru pa iyawo re ti pelu oyun osu meji, lo ba sa lo siluu oyinbo
Iyaale ile eni odun metalelogbon kan, Alimat Alaya, to n gbe lagbegbe Airport, niluu Ilorin, ti kegbajare lo sile-ejo, nibi to ti ni ki won tu igbayawo olodun mejo oun pelu oko oun, Mudasiru Alaya, ka nitori okunrin naa ti pa oun ti lo siluu oyinbo.
Obinrin ohun to ni ise tisa loun yan laayo salaye fun ile-ejo koko-koko kan niluu Ilorin pe oun ko nifee okunrin naa mo. O ni latigba toun ti wa ninu oyun osu meji loko oun ti gba ilu London lo, latigba naa si ni ko ti weyin wo rara.
O ni, ''Lati bii odun mejo bayii lo ti wa niluu London, to si ko lati wa sile. Odun 2007 lo ti kuro lorile-ede Naijiria, inu oyun osu meji ni mo wa nigba naa, omo si ti pe odun meje bayii ti ko foju kan baba re.''
Alimat so pe latigba toko oun ti lo, ko pe sori aago rara, bee ni ko fi nnkan kan ranse lati maa fi toju omobinrin kan soso toruko re n je Aishat toun bi fun un. O ni gbogbo awon ebi mejeeji lo ti da si oro naa, bee lawon kan ti ba a soro titi, sugbon ko si ayipada rere kankan.
Okunrin naa tabi ebi re kankan ko yoju sile-ejo, Alimat si ro ile-ejo lati pase fun oko re lati maa sanwo itoju omo kan to wa laarin won. O loun nikan loun n da bukaata naa gbo lati inu oyun titi digba tomo naa fi pe odun meje, oro ti su oun patapata.
Agbejoro fun olupejo, Ogbeni Taofik Olateju, ro ile-ejo lati sun ejo ohun siwaju lati fun oko obinrin naa laaye lati yoju sile-ejo.
Adajo Agboola Yusuf sun ejo siwaju, o si ni ki won mu iwe pada loo ba awon eeyan okunrin yii ko le yoju sile-ejo.
Posted By
Ifiranse Eleyi Je Thursday, June 18 @ 06:40:54 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
"Mudasiru pa iyawo re ti pelu oyun osu meji, lo ba sa lo siluu oyinbo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye
Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content
Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ