Gbagede Yoruba
 

 
Asiri tu, ase nitori obinrin ni won se gun Sina pa n 'Ilesa
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
Lati Owo Akoroyin Olootu


Asiri tu, ase nitori obinrin ni won se gun Sina pa n 'Ilesa


Bi iro ba lo logun odun, ojo kan soso ni otito yoo ba a. Leyin odun merin tokunrin kan ti won n pe ni Lekan ti gun enikeji re toruko re n je Sina lobe pa nibi ayeye Ikije Oba ilu Ilahun, Oba Lawrence Olamiju Ajayi, lopin ose ko koja yii ni ooto to wa nidii oro naa foju han gbangba niluu Ilesa tisele naa ti waye.


Iwadii Iwe Iroyin Yoruba fidi e mule pe Oloogbe Sina je omo egbe okunkun ti won n pe ni ‘Eiye', ti Lekan naa si je omo egbe okunkun mi-in ti a ko mo oruko re lasiko ti a n ko iroyin yii jo.Awon mejeeji la gbo pe won jo n fe omobinrin kan naa toruko re n je Opeoluwa, ati pe won ti jo leri sira won ni bii ojo meta seyin ki won too pade nibi ayeye Ikije Oba Ilu Ilahun.


Ore Oloogbe Sina to ni ka foruko boun lasiiri salaye fakoroyin wa lose to koja pe ki i se nitori pe Sina ko fun Lekan loti nibi ayeye naa gege bawon eeyan se n so kiri lo je ko gun un nigo, nitori Opeoluwa ti won jo n du mora won lowo ni, eyi ti Lekan ti kilo fun oloogbe naa pe ko fi omo naa sile foun, sugbon tiyen ko da a lohun. Eyi lo fi kuku gun un nigo lorun nigba ti won pade lode ariya.


O ni gbogbo oro naa lo soju oun, Lekan ti mura oloogbe naa lati Ilu Ibokun pelu obe olojumeji, gogongo lo si ti gun un. Saaju eyi ni Opeoluwa fi ilu Ibokun sile lo s'Ekoo, nibi to ti segbeyawo pelu okunrin mi-in, eyi to tubo mu kija to wa laarin Lekan ati Sina gbona si i.


Gbogbo akitiyan Iwe Iroyin Yoruba lati ba Opeoluwa ohun soro lori ero ilewo re lo ja si pabo fun bi ko se gbe ipe re.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 07:14:02 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Asiri tu, ase nitori obinrin ni won se gun Sina pa n 'Ilesa" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com