Gbagede Yoruba
 

 
Garuba ba omo odun meji lo po ni Somolu, lo ba ni oun kan ba a foso lasan ni
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
Lati Owo Akoroyin Olootu


Garuba ba omo odun meji lo po ni Somolu, lo ba ni oun kan ba a foso lasan ni


Ileese olopaa ti wo okunrin olokada kan, Garuba Abdulraman, eni ogbon odun lo si kootu majisreeti to wa l'Ebute-Meta lori esun ti won fi kan an pe o fipa ba omodebinrin omo odun meji kan taa foruko bo lasiiri lo po ni tipatipa, bee lo tun gba anti omo naa lesee ninu.


Gege bi Iwe Iroyin Yoruba se gbo, isele naa waye ni nnkan bii aago mokanla aabo aaro ojo kokanlelogun, osu keji, odun yii, lagbegbe Somolu, niluu Eko, iyen nigba ti iya omo odun meji ohun loo ki aburo re, Alimat Muazu, ti won si sadeede wa omo ti. Ibi ti won ti n wa a lenikan ti ta won lolobo pe oun ri Garuba pelu omo kan lowo. Kia ni won ti to okunrin omo ipinle Niger naa lo sile akoku kan to n sun.Sugbon si iyalenu won, won ko ri omo naa, bee ni okunrin yii ko ki won wole. Ibi tawon obinrin naa ti n gbiyanju lati wole ni Abdulraman ti fun Alimat to wa ninu oyun nipaa, bee lo so pe ti won ba sunmo oun tabi ile oun, oun yoo fada ge won si meji. Kia lawon obinrin naa ti loo fejo re sun awon olopaa to wa ni Somolu.


Nigba tawon yen debe ni won ri omo naa ninu ike omi kan ninu yara kan nile akoku ohun, bee ni won ri pata ati aso e, okunrin yii ko si woso sara. Ibi tomo naa ti gbiyanju lati dide ni ko ti le rin daadaa, kia ni won si ti gbe e lo sileewosan nibi tayewo ti fi han pe won ti ja ibale e. Eyi lo mu kawon olopaa maa wo Garuba lo sagoo won ko too di pe won tari e lo sile-ejo.


Lakooko ti agbejoro ijoba, Inspekito Richard Odige, n ka esun si i leti, o ni esun ifipabanilopo ni won fi kan an, bee lo tun dunkooko mo awon obinrin naa to fi fun oloyun nipaa ninu, eyi to lodi sofin ipinle Eko, to si tun nijiya nla ninu pelu.


Sugbon olujejo ni oun ko jebi nitori pe igbe lomo naa ya sara toun si ba a foso e, oun ko ba a sun rara. Bee ni agbejoro e, F. S. Oladele, ro ile-ejo lati faaye beeli sile fun un nitori esun ti won fi kan an je eyi ti won le gba oniduuro fun.


Adajo-binrin Agba O. I. Adelaja gba beeli afurasi odaran naa pelu egberun lona oodunrun naira ati oniduuro meji niye owo kan naa.


O sun igbejo mi-in sojo kejo, osu kerin, odun yii.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:17:22 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Garuba ba omo odun meji lo po ni Somolu, lo ba ni oun kan ba a foso lasan ni" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com