Gbagede Yoruba
 

 
Nitori ti ko gbe e jade lojo ayajo ololufe, iyawo dana sun oko e l'Ado-Ekit
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
Lati Owo Solomon Adewoye, Ado-Ekiti


Nitori ti ko gbe e jade lojo ayajo ololufe, iyawo dana sun oko e l'Ado-Ekiti


Opo eeyan loro naa si n ya lenu, bee ni awon kan ko tete gba eti won gbo nigba ti won gbo iroyin odidi iyawo ile to mo-on-mo dana sun oko e nitori pe iyen ko gbe e jade lojo ayajo ololufe to waye lose meji seyin.


Isele buruku naa waye laduugbo Idolofin, niluu Ado-Ekiti, lale ojo ayajo ololufe, iyen lojo kerinla, osu to koja yii. Arabinrin Bukola Ogidiolu to je eni ogbon odun ati oko re, Ogbeni Abimbola Ogidiolu ni isele naa sele si.


Gege bi awon toro naa soju e se so fun akoroyin wa, nise ni Bukola so fun oko e laaaro ojo naa pe ko gbe oun jade lale kawon loo se faaji, sugbon iyen pee de lati ibi ise, obinrin naa si so pe awon ale e to gbe jade lo je ko pe, ati pe oun yoo ko o logbon.Bo tile je pe Bukola ko fun oko e lounje lale ojo naa, eyi lo si mu ki Abimbola to je eni odun mejilelogbon to je awako akoyoyo ohun tete bo sori ibusun laimo pe iyawo re ti pese awon eroja ti yoo fi dana sun un sile.


Nise ni Bukola sadeede gbe epo bentiroolu to ti pese sile de oko e, to si da a si gbogbo ara e, bee lo sana si i lesekese. Ariwo ina ti okunrin yii pa lo mu kawon araadugbo tete jade si i, ti won si gbiyanju lati pa ina naa, bo tile je pe o ti jo gbogbo ara e.


Iya to bi Abimbola, Arabinrin Folake Ogidiolu, to je agbe so fakoroyin wa pe nise ni Bukola fee pa omo oun danu, bee ko sese maa hu iru iwa bee. O ni ni nnkan bii odun meta seyin bayii lawon mejeeji fe ara won pelu ayeye mo-mi-n-mo-o, sugbon lati igba naa titi di akoko yii, ko ti i si omo kankan laarin won.


“Ki i se igba akoko niyi ti ija yoo waye laarin omo mi ati iyawo re. Nise ni Bukola maa n lu u nilu bara, ti yoo si so pe oun yoo pa Bimbo lojo kan. Gbogbo akitiyan ni mo se lati mu ki Bukola fi omo mi lorun sile, sugbon ko gbo, nise lo maa n pe ara re ni omooba ilu AdoEkiti, nitori naa, ko si ohunkohun ti enikeni le se.  Iya Bimbo lo so bee.


Nigba ti akoroyin wa de ileewosan ekose isegun ijoba ipinle Ekiti to wa niluu Ado-Ekiti, ese kan aye ese kan orun ni Abimbola wa ti ko si le soro daadaa, bee lo jona koja siso. Nnkan omokunrin re gangan lo jona julo pelu bo se je pe nibe gan ni iyawo e da bentiroolu si, to si sana si i.


Bo tile je pe awon dokita ati noosi ti akoroyin wa fi oro wa lenu wo nibe so pe iyato ti n de ba Bimbo, sugbon eni to ba ri okunrin naa ninu irora nla to wa yoo ri i pe owo nla lawon idile naa nilo lati fi ra emi e pada ko si le je eeyan.


Iwadii akoroyin wa lagoo olopaa fi han pe ni kete ti isele naa sele ni Bukola ti fee sa lo, sugbon awon araadugbo fa a le awon olopaa lowo. Alukoro olopaa nipinle Ekiti, Albert Akinyemi, so fun akoroyin wa lofiisi re pe loooto ni isele naa waye, ati pe Bukola si wa latimole awon, nibi ti iwadii ti n lo lori isele naa, bee lo je pe ko ni i pee foju ba ile-ejo fun esun gbigbero lati seku pa oko re.


Gbogbo akitiyan akoroyin wa lagoo olopaa lati foju kan Bukola ko le ba wa soro lori isele naa lo ja si pabo pelu bi komisanna awon olopaa nipinle Ekiti, Ogbeni Taiwo Lakanu, se so pe asiko ko ti i to nitori iwadii si n tesiwaju.


Iya Bimbo waa rawo ebe sijoba atawon t'Olorun ba bukun fun lati ran oun lowo nitori ko si owo lowo oun, ati pe awon yoo nilo opolopo owo lati fi ra emi Bimbo pada. Bee lo je pe baba e naa ti dagba, ko le se ohunkohun mo.


 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 06:14:23 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"Nitori ti ko gbe e jade lojo ayajo ololufe, iyawo dana sun oko e l'Ado-Ekit" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com