Gbagede Yoruba
 

 
N'Ilesa, Aluko le iyawo e jade nile lori esun agbere
 
Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga Lati Owo Akoroyin OlootuN'Ilesa, Aluko le iyawo e jade nile lori esun agbereBi ile-ejo kaakiri orile-ede yii se n yanselodi bayii ni Ogbeni Aluko, eni ogota odun ti sedajo abele pelu bo se le iyawo re, Arabinrin Arike to je eni aadota odun jade nile lori esun agbere.

Eni toro naa soju e so pe l«Ojoru, Wesde, ose to koja yii ni Aluko ko ipa ati ikuuku bo Arike leyin to wole laago kan oru, ti ko si le salaye ohun to sele.

Nigba ti Iwe Iroyin Yoruba n ba Ogbeni Aluko soro nile re lopopona Omi-eran, nijoba ibile IlaOorun Ilesa, o ni aago mesan-an ale loun ti n pe Arike sori foonu, sugbon ko gbe e. Aago kan oru lo wole, ko si salaye nipa ode ariya to lo.

O ni o ti di gbogbo igba Arike lati maa lo ode ariya lai dagbere foun, igba to ba debe ni yoo pe oun sori foonu.

O so o di mimo pe oun ti ro oro, o si ti de gongo, eyi lo mu koun ko gbogbo eru e sita ko too ti ode ohun de lojo naa. O ni bi oun ba duro de asiko ti ile-ejo yoo fi opin si iyanselodi re, yoo ti pe ju.

Ninu oro ti Arike ba wa so nile ore re to wa, o ni ko si oko oun nile lasiko toun ba orebinrin oun lo sibi isinku iya re. O salaye pe erongba oun ni lati pada sile ni aago mejo ale, sugbon ore oun da oun duro lati ba a palemo. O ni ibinu oko oun loun ba pade, o si ti ko gbogbo eru oun jade. Nise lo ko igbaju bo oun tawon omo oun si gba oun kuro lowo re.

Lasiko ti a n ko iroyin yii jo, Arike ti pale gbogbo eru e mo lo sodo orebinrin re, bee lawon omo re meteeta (Aduke, Sanya ati Opeyemi) wa lodo baba won.

Ninu oro akobi idile naa, Aduke, o ni bo ba se wu won ki won se ara won, oun ko gbodo gbe leyin enikeni.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Tuesday, June 02 @ 05:57:49 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam
 

Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga:
O Sele! Iya Nimota Lo Oogun Ti Oyan E Fi Maa Tobi Si i, Loko Ba Da Eru E Sita: B


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹweAkole Atoka Agbo-Oro

Aburu Iwa Ese Idi Agbere Ati Iwa Pansaga

"N'Ilesa, Aluko le iyawo e jade nile lori esun agbere" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content

Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

EsinIslam The Muslim World Portal For Islamics, News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Quranic Islamic Articles, Radio, Audio Quran, TV Channels, Fatwa Rulings, Muslim News Newspapers Magazines Headlines Articles Forums Schools, Universities, Colleges, Mosques, Qur'an, Hadith, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Fasting Ramadan, Vidoes, Books On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com